AKO GBODO FI AKOKO SOFO
Tertulu agbejoro ni awon alatako Paulu be lati doju ko Paulu ati kristieni o wipe ‘Nitori awa ri okunrin yii, o je onidajo eniyan, eni ti o da rukerudo sile laarin gbogbo awon Juu ti o wa ni gbogbo aye ati olori eya awon Nasarene. Eni ti o gbidanwo lati ba tempili je ti awa si mu, ti awa fe ba se ejo gege bi ofin wa sugbon Lisia olori ogun de o fi agbara nla gbaa ni owo wa. (Awon Aposteli 24:5-7) Paulu pa Tertulu lenu mo sugbon o fi imoye gbe igbagbo re duro ni kootu, Paulu so fun agbejoro re pe ‘Sugbon eyi ni mo jewo fun o pe bi ona ti a npe ni adamo, bee ni emi nsin Olorun awon baba wa, emi ngba nnkan gbogbo gbo gege bi ofin ati ti a ko sinu iwe awon wolii. Mo si ni ireti sipa ti Olorun eyi ti awon funra won pelu jewo pe ajinde oku nbo, ati ti olooto ati ti alaisooto, ninu eyi ni emi si nse idaraya lati ni eri-okan ti ko ni ese-sipa ti Olorun ati si eniyan nigba gbogbo.
(Awon Aposteli 24:14-16)
EKO
Kristieni ti maa ni idojuko lati odo awon alaigbagbo, Olorun too, o si le gbe wa nija ti a ba ni idojuko tabi igbenija, niwon igba ti Olorun wa lori ite ko si agbara kan to le segun wa. Awa kristieni je omo imole, okunkun kan ko le bori wa, a kii se eniyan lasan a je iranse Olorun, Jesu Kristi ti fi ami-ororo yan wa lati ma wasuu ihinrere kakiri opin aye. Kristieni ko ni lati joko ti awon ohun ti ko se pataki, ki a si fi sofo awon akoko ti a ba lo fun ikede ihinrere kakiri agbaye. Kristieni ni lati yeara fun awon eniyan ti okan won yi ti won ko naani awon anfani ti nbe ninu ihinrere, onigbagbo ni lati sa gbogbo ipa fun wiwaasu ihinrere pelu awon eniyan, ki a si koha to dara si idahun won. A ni lati se ibewo awon eniyan, ki a ri wipe won mu iduro won deede ninu Oluwa, ojuse kristieni wa ni lati ni ipa ninu gbogbo ohun ti a ba nse , bi o se ye, a nilati kun fun adura ki a le ri ore-ofe ati agbara ti a o fi le duro ninu igbagbo titi laelae.
ADURA
Ni oruko Jesu Kristi, mo gba agbara ati ore-ofe lati tesiwaju wiwaasu ihinrere. Mo gba ifami ororo lati wasuu ihinrere lori ile, orile ede ati ahon, mo gba agbara Emi-Mimo lati duro ninu igbagbo ati ijewo mi ninu Jesu Kristi. Ni oruko Jesu Kristi mo jewo agbara mi lori Satani ati awon iranse re ati ohun elo re, mo pase ki won terba ni oruko Jesu, mo fi sofo gbogbo agbara ota ti aran lati pami lenu mo. Mo pase ki satani segbe ni gbogbo oro aye mi, ki emi le maa tan ihinrere kakiri opin aye, ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
