AYE TITUN
Olorun se iseda aye isinsiyi lati wa fun akoko die, yi o pa run gege bi Bibeli ti wi, Oluwa wipe Emi o mu gbogbo nnkan kuro lori ile naa patapata. Emi o mu eniyan ati eranko kuro, emi o mu eye oju orun kuro ati eja inu okun ati ohun idigbolu pelu awon eniyan buburu, emi o si ke eniyan kuro lori ile ni Oluwa wi. (Sefaniah 1:2-3) Jehofa seleri lati se ipaaro aye buburu yi pelu eyi ti o dara, ti yio je ibugbe fun awon eniyan mimo laelae, awon eniyan mimo Olorun ni yi o ni anfani lati gbadun aye titun. Olorun wipe nitori nigba naa ni emi o yi ede mimo si awon eniyan, ki gbogbo won ki o le ma ape oruko Oluwa lati fi okan kan sin in, lati oke odo Etiopia, awon elebe mi ani omobirin afunka mi, yoo mu ore mi wa. Ni ojo naa ni iwo ki yoo tiju nitori gbogbo ise re, ninu eyi ti iwo ti dese si mi nitori nigba naa ni emi o mu awon ti nyo ninu igberaga re kuro laarin re, iwo ki yoo si gberaga mo ni oke mimo mi. emi o fi awon otosi ati talaka eniyan sile pelu laarin re, won o si gbekele oruko Oluwa, awon iyooku Isreali ki yoo huwa ibi bee ni won ki yoo soro eke, bee ni a ki yoo ria hon arekereke ni enu won sugbon won o jeun, won o si dubule, enikan ki yoo si deru ba won.
(Zefaniah 3:9-13)
EKO
Aye isinsiyi ki yoo wa titi laelae sugbon yi o wa si ipin ni akoko ti Oluwa ti yan, Jehofa yi o da aye titun ti ko ni buburu tabi idibaje, iye awon ti o fi otito sin Olorun ti won si gba eri Jesu Kristi ni yi o ye lati wo aye titun ati orun titun ti a o da sile. Gbogbo awon onise ese ki yi o ye fun paradise (Aye titun) awon eniyan buburu ni a o ke kuro, won o ni ipin won ninu adagun ina. (Ifihan 21:1-3)
ADURA
Olorun olufe ka mi ye fun ijoba re, mu ese mi duro ni enu ona re ki nle maa gbe igbe aye ti o ba idiwon re mu. Je ki Emi-Mimo re to mi ni gbogbo otito, ki a le ko oruko mi sinu iwe iye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
