GBIGBA ADURA SI OLORUN
Jesu gbadura fun awon omo ehin re, o si gbadura fun ara re. O so fun peteru pe simoni, simoni, wo o, satani fe lati ni o, ki o le ku o bi alikama. Sugbon mo ti gbadura fun o, ki igbagbo re kio ma ye, ati iwo nigbati iwo ba si yipada, mu awon arakunrin re ni okan le.
(Luku 22: 31-32).
Jesu tun ro awon omo ehin re lati maa gbadura fun ara won, o si fi ikoni re sinu ise. Bibeli wipe, o si jade, o si lo bi ise re si oke olifi, awon omo ehin re too lehin. Nigba ti o wa nibe, o wi fun won pe, e maa gbadura, ki eyin ki o ma se bo sinu idanwo. O si fi won sile niwon isokan kan, o si kunle o si ngbadura, wipe, baba, bi iwo ba fe, gba aago yi lowo mi, sugbon ife ti emi ko, bi ko se tire ni ki a se.
(Luku 22: 39-42).
EKO
Kristeni ko ni ohun ija miran ju adura lo. A nilati gbadura lati le bori iru igbenija ti o ba de si wa. Ki a ma so pe ohun kan kere tabi tobi lai fi sinu adura. Ti a ba gbadura si olorun, o tunmo si pe a gbekele olorun fun iranlowo, a si nduro de idahun. Adura tumo si gbigba olorun alagbara gbo lati yanju ibeere wa. Otito patapata ni pe ngbo gbogbo adura. Yio dahun gbogbo ebe awon omo re, nigba miran idahun re le je beeni, bee ko tabi ni ojo iwaju.
ADURA
Beeni mo gbagbo pe olorun ni agbara nla ti ko ni odinwon lati yanju gbogbo ebe wa. Olorun le se ohun gbogbo ati temi. Nitorina mo gbadura ki olorun ki o wo pale gbogbo oke isor ti nbe ninu aye mi. Mo be olorun ki o segun ese, ailera, osi, ati ohun buburu ti o ba wa ninu aye mi. Mo si nbe olorun ki o fi ifami ororo yan mi, kin nni ore ofe lati wa ni alaafia, ki ndi oloro ni gbogbo iyoku aye mi. Ki olorun fun mi ni ore ofe lati le sin in ni gbogbo aye mi ni otito. Ni oruko Jesu kristi ni mo beere. Amin.
