GBIGBA ADURA
Dafidi ko lati gbara le iranlowo eniyan nigba wahala, sugbon o kigbe si olorun fun iranlowo, o si gba a. Nigba wahala, Dafidi wipe saanu fun mi, olorun, saanu fun mi, nitori ti okan mi gbekele o, looto, ni ojiji iye apa re ni emi o fi se aabo mi, titi wahala wonyi yi o fi re koja. Emi o kigbe pe olorun oga ogo si olorun ti o se ohun gbogbo fun mi. Oun o ranse lati orun wa, yoo si gba mi bi eni ti nfe gbe mi tile nkegan mi. Olorun yoo ran aanu re ati otito re jade
(Orin Dafidi 57:1-3).
EKO
Adura je ohun elo ti kristeni ni lati maa mu lo lojoojumo. A nilati maa yin olorun ni akoko adura, ki a si so edun okan wa fun un. Nigba wahala, kii se pe ki a kigbe si olorun lati fi irora wa han, sugbon a o pe olorun si isoro ti a ndoju ko. Adura je pipe olorun nigba isoro wa ki o si ba aini wa pade
ADURA
Olorun olufe, jowo ko mi bi mo se le maa gbadura. Ran mi lowo lati le ma so edun okan mi ni igbakigba. Si je kii ni igbagbo pe oo dami lohun nigba ti mo ba gbadura si o. Jowo fun mi ni ore ofe lati le je anfani adura, ki o si dara fun mi ni gbogbo ojo aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
