A NILO IGBAGBO TI KO KIN YE LATI BA OLORUN RIN
Awon Kristeni ni ilu Berea fiitumo Kristenihan, wonsi je apere to daara fun wa lati tele. Bibeli wipe, awon wonyi si ni iyin ju awon ti Tessalonika lo ni ti pe won fi tokantokan gba oro naa, won si nwa inu iwe –mimo lojojumo bi nnkan wonyi ri bee. Nitori naa pupo ninu won gbagbo, ati ninu awon obinrin Hellene Olola, ati ninu awon okunrin, kii se die. (Awon Aposteli 17:11-12)
EKO
Igbe aye Kristeni je iise, ki se ni oro nikan. Onigbagbo ni lati maa fi si ojuse, oye won ninu bibeli nipa idapo won pelu Olorun ni pipe ati nini ife si awon elomiran. Enikeni ti o ba je Kristeni ni lati maa wa inu iwe smimo lojojumo, ki won si mu si ise, ohun ti won nko. O se Pataki ki Kristeni se ayewo ohun ti won ko pelu bibeli. Eko tabi imo ti ko ba wa ni ibamu pelu bibeli ni ki won ko lesekese. Awon eko ti o ba wa ni ibamu pelu bibeli ni ki a yayo le lori. Gbogbo omo Olorun ni a fun ni ase lati sin Olorun ni Emi ati ni otito (Johanu 4:24)
ADURA
Olorun Olufe, mo fe je ojulowo Kristeni ti yio maa keko oro re ni ojojumo, ki nsi fi sinu ise ninu aye mi. Je ki emi ni oye ilana bibeli, je ki emi le pa ofin re mo, ki emi si ni idapo to joju pelu re. Ran mi lowo lati je olotito Kristeni, si bukun mi ni gbogbo igbese mi lati te o lorun. Fun mi ni ore-ofe lati je olufokan sin Kristeni fun gbogbo ojo aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
