OLORUN LO GAA JU
Otito gbolohun ni lati wipe, Oluwa joba je ki awon eniyan ki o wa riri, o jokoo lori awon kerubu, ki aye ki o ta gbo-on-gbon-on (Orin Dafidi 99:1)
EKO
Olorun ni o gaju ninu ohun gbogbo ti o wa. Gbogbo ohun ti o wa ni oju ofurufu loke ati ni aye, nbe ni abe agbara re. Olorun da ohun gbogbo, o ronu, o si da won, lai gba ase lowo enikeni tabi nibikibi. Nitori naa, gbogbo eniyan nilati wa riri labe agbara nla re, ki a si yin oruko re. Je ki alaaye okan ki o kigbe ‘Halleluyah Olorun njoba’.
ADURA
Olorun Olufe, mo beere, jowo fun mi ni ore-ofe ati okun lati le yin o, lati inu okan mi wa. Je ki emi le maa yin o titi ti emi yio mi eemi ti o gbehin ninu aye yi. Je ki eri didara re kun enu mi titi laelae. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
