OMI IYE
Obinrin kan ti o ba Jesu Kristi pade ni eti kanga, lo ya lenu lati gbo lenu Jesu Kristi wipe oun ni omi iye. Ninu iporuru okan ti arabinrin yi ni Jesu tun salaye wipe enikeni ti o ba mu ninu omi yii, orungbe yoo si tun gbe e. Sugbon enikeni ti o ba mu ninu omi ti o fi fun un, orungbe ki yoo gbe e mo lae, sugbon omi ti emi o fi fun un yoo di konga omi ninu re, ti yoo ma sun si iye ainipekun. (Johanu 4:13-14).
EKO
Jesu Kristi ni omi iye, ti o wa lati odo olorun. Enikeni ti o ba mu ninu omi yi, oungbe ki yio gbe mo laelae. Agbara Jesu to lati mu oungbe ti ara kuro. Olugbala yi o fun enikeni ni iye ayeraye, ti o ba gbaa gege bi oluwa ati olugbala re. Yi o bukun onigbagbo pelu iye ayeraye, yi o si fun won ni ifokanbale ni orun titi lae. Sugbon enikeni ti o ba ko igbala ti Jesu Kristi pese, ki yi o ri aye lati wo orun. Iru eni bee yio ni ipin ni orun ina apadi, nibi ti idaloro yi o wa titi lae.
ADURA
Jeus Kristi olufe, mo fe lo dorun, emi ko fe lo si orun ina apadi. Mo jewo re, mo si gba o bi oluwa ati olugbala mi. Lati oni lo, mo yonda gbogbo aye mi, mo si pinu lati sin o ni gbogbo ni gbogbo igbe aye mi ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
