ISOKAN
Bibeli gba Kristeni niyanju lati wa ni isokan, a koo wipe,Kiyesii o ti dara, o si ti dun to fun awon ara lati maa jumo gbe ni irepo. O dabi ororo ikunra iyebiye ni ori, ti o san de irugbon, ani irungbon Aaroni, ti o san si eti aso re. (Orin Dafidi 133:1-2)
EKO
Isokan se Pataki laarin awon Kristeni lati lee gba ibukun Olorun. Olorun yio b’ola fun adura isokan, yio si je ki awon omo re jewo agbara re laarin won. Akunwosile ifami-ororo wa ninu isokan. Jehofa ko ni fa ibukun re sehin fun awon ti won ba nrin papo ninu ife. Nitori naa gbogbo omokunrin ati omobinrin Olorun ni lati mo wipe o je ase lati orun wa lati je ki ife wa ninu agbo Kristi, ki oruko Olorun lee di gbigbega ni gbogbo igba.
ADURA
Olorun olufe, jowo pa awon arakunrin mo ninu ife, ran wa lowo lati le pati si apakan aisokan wa, ki a le papo yin o pelu okan kan. Yonda akunwosile ore-ofe ifami-ororo yan le gbogbo ara, ki a le sa gbogbo ipa lati polongo oruko re ninu ife. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
