IDARIJI
Jesu Kristi pe Kristieni nija lati dariji ohun kohun yio wu ti yi o na wa. O wipe ‘E maa kiyesarayin, bi arakunrin re ba se ba wi, bi o ba si ronupiwada, dariji. Bi o ba se o ni eemeji ni oojo ti o si pada to o wa ni eemeje ni oojo pe, mo ronupiwada dari jii. (Luku 17:3-4)
EKO
Idariji tumo si ki a dari ji enikeni ti o ba se wa. Ani lati ko eko lara Olorun ti o ran omo re Jesu Kristi lati ku fun wa ki o le dari ese wa ji wa. Olorun jiya idojuti nipa iwa ese omo eniyan, sibe o ran omo re lati ku fun wa. Olorun dari ese wa ji wa laibeere owo tabi ohunkohun lowo wa. Bakan naa o ye ki a dariji enikeni ti o ba se walai gba ohunkohun lowo won. Olorun yi o bukun wa bi a ba le fi oore san ibi fun awon to ba se wa.
ADURA
Olorun olufe jowo ran mi lowo lati le dariji awon ti o se mi, kinsi le fi okan imore han si won. Mo mo wipe, eyi le soro die sugbon mo mo pe Emi Mimo re yi o wo mi ni agbara lati se eyi ti o ba to. Jowo fun mi ni agbara ki oju si ti Satani nigba ti o ba ri bi mo se ndariji awon ti o ti se mi. ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
