ALAANU NI OLORUN
Olorun dara, o je alaanu, onsin dari ese ji ni. Orin Dafidi wo didara Olorun o si wipe ‘Nitori pe bi orun ti ga si ile bee ni aanu re tobi si awon ti o beru re, bi ila-orun ti jinna si iwo-oorun bee ni o mu irekoja wa jinna kuro lodo wa. Bi baba ti se iyonu si awon omo bee ni Oluwa nse iyonu si awon ti o beru re.
(Orin Dafidi 103:11-13)
EKO
Olorun ni o ni agbara ju ninu eda alaye, o si lee se ohun ti o ba wuu. Bi o se tobi to nipa agbara lati fi iya je elese, o setan lati saanu ki o si dariji enikeni ti o ba le re ara re sile ki o wipe ‘E ase binu’ Olorun yi o dariji, yi o si muu wasipo elese ti o ba bebe fun aanu, yi o si fun iru eni bee ni agbara lati maa le otito. O dun moni lati mo wipe Olorun ko ni lo titobi agbara re lori elese yala eyi, yi o fi ife re han si awon elese, yi o si fun won ni anfani lati ronupiwada, yi o si dari ese won ji won. Bakan naa, Olorun ko le dariji elese laisi irubo, Jesu Kristi ti yonda ara re, elese ti o ba ronupiwada ti o si se ijewo igbagbo ninu Jesu Kristi pe omo Olorun tooto nii se, yi o ri idariji ese gba, a o si gbaala. (iru eni bee yi o ri iye ayeraye gba)
ADURA
Olorun olufe, mo kabamo gbogbo ese mi, mo si ronupiwada kuro ninu won, mo fun o ni aye mi loni, mo si jewo igbagbo mi ninu omo re Jesu Kristi ni Oluwa. Mo Gbagbo pe Jesu Kristi ku, o jinde ki o baa le fun mi ni iye ainipekun. Mo jewo igbagbo mi ninu re, mo si gbaa bi Oluwa ati olugbala mi, mo seleri lati maa sin Jesu titi ojo aye mi. Amin.
