TITOBI NI OLORUN OPOLOPO IYIN NI O TO SI
Gbogbo eniyan lo ye ki won maa yin Olorun, o ye ki a keko lara onisamu (Orin Dafidi) ti o wipe fi ibukun fun Oluwa iwo okan mi, Oluwa, Olorun mi, iwo tobi jojo, ola ati ola-nla ni iwo wo ni aso. Eni ti o fi imole bora bi aso, eni ti o ta orun bi aso tita. Eni ti o fi omi se ite igi aja iyewu re, eni ti o se awosanma ni keke re, eni ti o n rin lori apa iye afefe. Eni ti o se efufu ni onise re, ati owo –in ni iranse re. (Orin Dafidi 104:1-4)
EKO
Jinjin ogbo Olorun koja oye omo eniyan, ko si seese lati diwon re. Agbara Olorun koja ohun ti oluko kan le salaye. O wa se Pataki ki gbogbo eniyan bowo fun Olorun, ki a si maa yin fun didara re.
ADURA
Mo yin O Olorun, fun didara si awon eniyan ti o da. Didara re si awa eniyan ko lonka, nitori naa, mo mo riri re. Mo beere ki okan mi maa mo didara re sii, ki emi le maa yin o sii. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
