TI O BA DIDE FUN OLORUN, WA KA ERERE
Danieli ati awon omo Heberu meta (ti apeje won nje Sadraki, Mesaki ati Abednego) pinu ni okan won, wipe oun ko ni fi ounje adidun ati –waini lati odo oba Nebukadnessari ba ara ounje. Won yan lati gboran si Olorun ju ki won je ounje awon Babeli. Danieli, gegebi asoju awon ti o ku wipe Dan awon omo-do re wo emi be o, ni ijo mewaa, ki o si je ki won ki o maa fi ewa fun wa lati je ati omi lati mu. Nigba naa ni ki a wo oju wa niwaju re, ati oju awon omo tin je ounje adidun oba, bi iwo ba si ti rii si, bee ni ki o se si awon omo-odo re. Beeni o gba fun won ni oran yi, o si dan won wo ni ijo mewaa. Niwon ti Danieli ati awon arakunrin re gbekele Olorun, Olorun bukun won pada. Bibeli wipe bi o se ti awon omo mereerin wonyi ni, Olorun fun won ni imo ati oye ni gbogbo iwe ati ogbon, Danieli si ni oye ni gbogbo iran ati ala. Nigba ti o si di opin ojo ti oba ti da pe ki a mu won wa, nigba naa ni olori awon iwofa mu won wa siwaju Nebukadnessari. Oba si ba won soro, ninu gbogbo won, ko si si eni ti o da bi Danieli, Hananiah, Misaeli ati Asariah, nitori naa ni won fi nduro niwaju oba. Ati ninu gbogbo oran ogbon ati oye, ti oba nbeere lowo won, o rii pe ni iwon igba mewaa, won sari ju gbogbo awon omoye ati ologbon ti o wa ni gbogbo ile ijoba re lo (Daniel 1:12 – 14, Daniel 1:17-20).
EKO
Olorun nbowo fun awon ti o ba ni igbagbo sii, yio duro ti won lati rii wipe a ko doju ti won. Ni akoko ati igba yi igbagbo ti o duro giri, ko wopo mo. Olorun nfe awon ti yio wuu ni ori nipa igbese won. Jehofa nwa ohun ti yio gbogun ti awon ohun ti o tako ife re. Awon ti o ba duro ti Olorun ni a o b’ola fun, a o si bukun won ju awon elegbe won, a o si ko oruko won sinu iwe didara Olorun. Nitori naa awon omo Olorun ni lati sun mo bibeli won. A ni lati maa wa inu iwe mimo, ki a le mo otito Olorun. Igba aye wa gbudo se dede pelu Bibeli, ki tite Olorun lorun je koko fun wa. Beeni sise daradara wa le je okunfa ina fun awon agbo miran, won lee bu wa, se inunibini si wa, pon wa loju. Lehin re ade ogo ododo nduro de wa ni orun. Awon ogun orun yio ye wa si, bi a ba di igbagbo wa mu.
ADURA
Olorun Olufe, se mi ni akikanju Kristeni ti ko ni gba ohunkohun ti o kere si ireti Olorun. Jowo se mi ni eni ti o gbagbo, eni ti o le farada inira, ti okan re si romo ojuse inu bibeli. Je ki ijewo ati ojuse mi ba ife re mu, ki oruko re lee di gbigbe ga ni aye ese yi. Se mi ni asoju re bi imole ninu aye okukun buburu yi, ki eri isegun re wa ni enu mi, jowo je ki emi ni idapo ti ose dede pelu re. Ki a si yayo mi ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere, Amin.
