IRETI AMUYE FUN IPO ADARI
Paulu salaye awon amuye fun enikeni ti o ye fun ipo alagba ninu ijo. Paulu wipe, bi enikeni ba se alailegan, oko aya kan, ti o ni omo ti o gbagbo, ti a ko fi sun fun wobia, ti won ko si je alagidi. Nitori o ye ki Bisoobu je alailegan, bi iriju Olorun, ki o ma je ase-tinu-eni, oninu fufu, omuti, aluni olojukokoro. Bi ko se olufe alejo sise, olufe awon eniyan rere, alairekoja, olooto, eni mimo eni iwontunwosi. Ti o ndi oro otito mu sinsin eyi tii se gege bi eko, ki oun ki o le maa gbani-niyanju ninu eko ti o ye kooro, ki o si le maa da awon asoro – odi lebi (Titu 1:6-9)
EKO
Gbogbo alagba Kristeni ni o ye ki o maa gbe igbe aye ti o ye fun ope. Won ni lati huwa ti yio je arikose fun elomiran. Ni won igba ti awon alagba ijo je asoju Olorun, won ko ni huwa ti yio si awon eniyan lona. Gbogbo iwa ati ojuse (Kristeni) alagba ni lati se eyi ti yio fa awon eniyan wa si odo Olorun.
ADURA
Olorun Olufe mo gbadura fun gbogbo alagba Kristeni lati le maa gbe igbe aye arikose. Jowo ran won lowo lati lee bori gbogbo ipenija ti o ba ndoju ko won. Jowo kun won pelu Emi Mimo ki won le dari awon eniyan re gege bi ife re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere, Amin.
