SISAN EJE RE NI AKOKO LATI GBA IBUKUN RE
Olọrun nfẹ ki awọn Ọmọ Israeli bowọ fun oun, ki wọn si mu ẹjẹ wọn ṣẹ. wọn ko gbodọ foju fo ẹjẹ wọn, Sugbọn ki wọn san an ni akoko to yẹ. Olọrun sọ wipe aile mu wa si ṣise, ẹjẹ awọn Ọmọ Israeli ni yi o ja si irufin. Oun o si fi ipa mu wọn lati mu ṣẹ. Olọrun sọ fun awọn Ọmọ rẹ ‘Nigba ti iwọ ba j̣ejẹ kan fun Oluwa Olọrun rẹ, ki iwọ ki o ma ṣe fasẹyin lati san an; nitori pe Oluwa Olọrun rẹ yi o bere rẹ nitootọ lọwọ rẹ, yoo si di ẹsẹ si o lọrun. Sugbọn bi iwọ ba fasẹyin lati jẹejẹẹ, ki yoo di ẹsẹ si o lọrun. Ohun ti o ti ete rẹ jade, ni ki iwo ki o pamọ, ki o si se gẹgẹ bi iwọ ti jẹejẹe fun Oluwa Olọrun re, ani ọrẹ if̀ẹ – atinuwa ti iwọ ti fi ẹnu rẹ ṣe ileri. (Deuteronomi 23:21-23).
ÈKỌ́
Baba wa ti nbẹ lọrun jẹ Olọrun ti nmu ileri rẹ sẹ. yi o mu wa si imuṣẹ gbogbo ileri ti o ti se fun awọn Ọmo rẹ, nitori ijolootọ rẹ. Olọrun ti o nṣe ileri nfẹ ki awọn Ọmo re ṣe bẹẹ ninu iṣe ati iwa wọn. O fẹ ki awọn Ọmo rẹ ki wọn bowo fun Ọrọ wọn, ki wọn si mu ileri wọn ṣẹ. Jehofa nfẹ ki o jẹ asa wa lati ma san ẹjẹ wa. Yi o bere lọwọ Ẹnikeni ti o ba kọ lati mu ileri rẹ ṣẹ. O seni lanu pe opọlọpọ ni nṣe ileri ti won si yara gbagbe wọn. Opọlọpọ eniyan ma nṣe ileri lati lo owo wọn, akoko wọn ati ohun ini wọn fun Olọrun nigba ti wọn ba nfẹ iranlọwọ, ti wọn nkọ lati s̀an ẹjẹ wọn. Opọlọpọ maa nṣeleri pe ‘Olọrun, ti o ba le mumi la akoko inira yi ja, ẹmi yi o fi iyoku aye mi sin o, Sugbọn wọn ki mu ileri wọn ṣẹ lẹhin ti adura wọn ba gba. Olọrun ko gbagbe ileri kileri ti ẹda le ṣe, yi o bere irapada awọn ileri/ẹjẹ ti a ba ṣe, o si le jẹ idena si ibukun Ọjọ ola awọn eniyan bẹ. Nitori naa Onigbagbo nilati ma wariri niwaju Oluwa ni gbogbo igba.
Ki olukuluku ki o kiye si ̣Ọrọ ẹnu wa, ki a maṣe ṣo isokusọ pẹlu ẹnu wa. A ni lati s̀an ẹjẹ wa ni lakoko ti yi o ṣe itẹwọ gba. Ẹ je ki a mọ pe, ipe wa lati san ẹjẹ wa fun Olọrun, kii se fun aini rẹ. Jehofa kii ṣe otoṣi, kii ṣ̀e awọn ẹbun wa ni yi o fi ṣ̀aye. O nfẹ ijolotitọ wa, ki o le tu ẹbun rẹ si aye wa. Nigba ti aba fihan pe a duro le Ọrọ wa, Ẹlẹda yi o tu ibukun rẹ lewa lori fun ilo wa ati fun iselogo orukọ rẹ.
ADURA
Olọrun ran mi lọwọ lati le bu ola fun Ọrọ mi ki nsi mu ileri mi ṣẹ niwaju rẹ. maṣ̀e jẹ ki nṣe ileri ofo ti ko ni tẹ o lọrun. Dari jimi awọn ẹjẹ ti atẹhinwa ti nko mu ṣe, se idapada awọn anfani ti mo ti padanu nitori aimuu ṣẹ. fun mi ni anfani nigba keji, ibeerẹ otun irapada ẹjẹ mi ki inu rẹ dun, ki o si bu kun mi. lati akoko yi lọ, fun mi ni okun ki nle tẹ ọ lọrun pẹlu ọọre mi, ki o mu inu rẹ dun lati bukun mi sii, kii nsi ma jẹ anfani ọrọ rẹ fun iyoku aye mi. ni Oruko Jesu Kristi. Amin.
