SE AWARI IJINLE ONA ISEGUN TI JESU LORI SATANI
Awọn Farisi jẹ alatako Jesu Kristi, wọn nlo ẹsin wọn gẹgẹ bi agabagebe lati fi owu ati itara wọn han. Awọn Farisi ko dẹkun lati da Jesu duro fun opọ akoko, ki wọn ma tẹléé kiri ki wọn ba le ri ẹsun ka si lẹsẹ lori iṣẹ iranṣẹ rẹ. Ọrọ Olọrun sọ diẹ ninu ojuṣ́e awọn Farisi ‘O si śe ni Ọjọ isimi miran, ti o wọ inu sinagogu lọ, o si nkoni, Okunrin kan si nbẹ nibẹ ti owọ rẹ otun rọ. Ati awọn akọwe ati awọn Farisi n ṣọ ọ bi yio mu larada ni Ọjọ isimi, ki wọn ki o le ri ona ati fii sun.
‘O si ṣe ni Ọjọ isimi keji lẹyin ekini, Jesu kọja laarin Oko ọka awọn ọmọ – ẹhin rẹ si nya ipẹ ọka, wọn nfi owọ ràà jẹ, awọn kan ninu awọn Farisi si wi fun wọn pe, Éeṣe ti ẹyin fi nṣe eyi ti ko yẹ lati ṣ́e ni Ọjo isimi (LUKU 6:6-7, LUKU 6:1-2)
ÈKỌ́
Satani fẹran lati mu ki Oluf̀isun íṣ̣ẹ ibi rẹ ma tẹle awọn eniyan mimọ ki wọn ba le ri ijakulẹ ninu iṣẹ iranṣẹ wọn. Ota yio ma gbiyanju lorisirisi ona, yi o ma lepa ki won le subu, yi o ma ju Oko si wọn boya okan yi o ba wọn. Nitorina, lati le bori Satani, Onigbagbọ ni lati wa ninu ẹmi (kiyesara), kun fun adura, ki wọn si kun fun ẹmi mimọ. Sugbọn Onigbagbọ ko gbudọ gbagbe pe ero Satani kii nṣe lati fa irewẹsi Ọkan Sugbọn lati jale ati pa ati lati pa igbala wa. (JOHANU10:10) Ni wọn igba ti awa Onigbagbọ ba kun fun adura ati ikiyesara, a le tẹle apẹrẹ Jesu ni ohun gbogbo ti a ba nṣe. Fun apẹre, Satani lo awọn Farisi lati gbogun ti Jesu.
* Jesu pe awon Farisi ni – Onigbagbọ
* Jesu pinu lati ma ṣe iṣe Olọrun – Onigbagbọ ko gbudọ dawọ duro ni ṣise if̀e Oluwa.
* Jesu ni ígba gbogbo ma nlọ síbí idakẹ jẹẹ lati lọ gbadura fun Ọkan ati isọji lẹhin iṣẹ iranṣẹ – Onigbagbọ ni lati ma kun fun imisi ati agbara ninu adura.
* Jesu ṣe ayipada agbegbe lati yẹra fun ariwo awọn Ota – Onigbagbọ ni lati ṣe ayipada eto lati bori Ọta.
ADURA
Olọrun fun mi ni agbara lati le bori Satani ati le bori Ogun aye fun iyinlogo orukọ mimọ rẹ. ati pẹlu fun mi ni agbara ki nle pinnu ki nma se da si Satani ati awọn iranṣẹ ibi rẹ. Jẹ ki ẹmi mimọ ro mi ni agbara, ki nduro lai yesẹ, ki ntẹsiwaju lakoko idojukọ ati ipenija. Ati pẹlu, ki ẹmi mimọ ro mi ni agbara, ki ma kiyesara, kun fun adura ki nle ma ṣe aseyori ninu iṣẹ iranṣe, ki imolẹ ihinrere le tan kalẹ orilẹ agbaye. Nigba ti ire ije aye mi ba pari, je ki emi le duro niwaju re ni Ọ̣run ki nsi gbọ pe ku isẹ, kabọ sinu ayọ Oluwa rẹ. Mo bẹbẹ ibeere mi ni Orukọ Jesu Kristi. Amin
