SE AKIYESARA; GBE IGBE AYE NI IBAMU PELU ORO OLORUN
A ngba Kristeni kookan niyanju lati kiyesara, ki a mase bo sinu idewo awon asa ati ise aye ti o ngbile ni awujo wa. Bibeli wipe ‘sugbon e maa gba ara yin niyanju ni ojojumo, niwon igba ti a ba npe e ni oni, ki a ma baa se okan enikeni ninu yin le nipa etan. Nitori awa di alabapin pelu Kristi, bi awa ba di ipilese igbekele wa mu sinsin, titi de opin. (Heberu 3:13-14).
EKO
Ilana Ere Ije Kristeni je ise to duro le igbe aye Jesu Kristi. Awa Kristeni ni lati josin tokan tokan. A ni lati tele Bibeli, ki a si lo igbe aye wa ki o ba ife Olorun mi. Niwon bi Igbagbo Onigbagbo ti je irin ajo to lo si odo Olorun, a ni lati kiyesara bi a ti nrin. Ko ye ki a so igbagbo nu, tabi gbonjege ninu eko bibeli, a nilati duro ninu otito. A ko gbodo gba, idanwo tabi inunibini laaye ki a kun fun adura ati ifunra, lati le dojuko, ki a si segun ipenija ti oba doju ko igbagbo wa ninu Jesu Kristi. A nilati kun fun adura ati kikun fun Emi Mimo ni ojoojumo.
ADURA
Olorun Olufe, mo je Kristeni, o je ojuse mi lati duro, ki emi si peye ojuse Bibeli. O wu mi lati fi aye mi sin o, emi ko fe gbonjege igbagbo mi labe bi o ti wu ki o ri. Emi ko fe tele ohunkohun ti o ba tako Bibeli, sugbon mo fe duro ninu otito ki emi si se ohun ti o ba fe. Jowo fun mi ni okun nipase Emi Mimo lati je Kristeni tooto. Fi ifami ororo ore ofe yan mi ki emi lee yayo pelu re ni ojo ikehin. Jowo se ona mi ni rere ni ile aye, ki emi ba lee sin o sii. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
