B’OWO FUN AWON IRANSE OLORUN NIPA PIPESE FUN AINI WON.
Awon iranse Olorun se Pataki ni okan Olorun, bakannaa, a nilati b’ola fun won. Paulu salaye bo ti ye ki a maa pese fun aini awon iranse Olorun, o wipe Eyin ko mo pe awon ti nsise nipa ohun mimo, won a maa je ninu ohun ti tempili, ati awon ti nduro ti pepe won a maa se ajopin pelu pepe. Gege bee ni Oluwa si se ilana pe, awon ti nwaasu ihinrere ki won o si maa je nipa ihinrere. (1 Korinti 9:13-14).
EKO
Asa fi ko wa ki a maa se itoju awon iranse Olorun ti won nsise lori wa. Awon iranse Olorun a maa gbadura ati gba awe nitori wa. Won a si maa wa oju Olorun, ki won le fi oro Olorun bo wa bo ti ye, eyi tin se ounje iye. Awon iranse Olorun je Asoju Olorun, o ye ki a b’owo fun won. Owo ti a ba fun iranse Olorun, Olorun ni a nfi fun. Nitori naa, awa onigbagbo ni lati lo gbogbo anfani ti a ba ni lati se itoju awon (iranse Olorun) olori wa ninu Emi, ti won wa lori wa.
ADURA
Olorun Olufe, mo mo wipe awon Ajinyin rere (Oniwaasu) je Asoju re ni ile aye, nitori naa fun mi ni ore-ofe lati maa b’ola fun won. Je ki emi sa gbogbo ipa mi pelu ohun ti mo ba ni lati se itoju won, ki emi si je ogbeniro fun ebi won. Mo gbadura ki o fun awon iranse re ni ifokanbale ati ayo, ki won le maa tesiwaju ninu ise omo eniyan, ati fun ijoba re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
