PIPA OFIN OLORUN MO
Olorun soro si awon alaigboran awon omo re eyi lo fi ran Wolii re lati kede ibi ti yi o subu lu won, Olorun so fun Wolii Hosea ‘Fi ipe si enu re yoo wa bi idi si ile Oluwa, nitori won ti re majemu mi koja, won si ti ru ofin mi won o kigbe si mi pe Olorun mi, awa Isreali mo o, Isreali ti gba ohun rere sonu ota yoo lepa re
(Hosea 8:1-3)
EKO
Olorun ko ni gba abetele, ko si magomago tabi itanje ti a le se ti yi o fi yi iwa mimo re pada. Olorun ti so ero okan re nipa ohun gbogbo ati nipa wa, o ni ki gbogbo eniyan sise ni ododo niwaju re ki won ba le di eni ibukun. Enkeni ti o ba ko lati pa ofin Olorun mo ni a o pe lejo ti a o si fiya je ni ojo idajo ikehin Olorun. O se Pataki ki a mu inu Olorun dun ninu ohun gbogbo ti a ban se ki o ba le bukun wa.
ADURA
Olorun olufe jowo ran mi lowo kin le beru re, kinsi sin o ni otito. Ran mi lowo lati pa gbogbo ofin re mo, jowo ka mi ye lati le je alabapin ninu anfani re, kin mase ni ipin ninu ifiya-je re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
