PA ARA RE MO NI MIMO SI OLUWA
Olorun korira pansaga ati agbere, o si pase ki awon omo re yera fun won. Bibeli wipe nitori eyi ni ife Olorun, ani wiwa ni mimo yin, pe ki eyin ki o takete si agbere. Ki olukuluku yin le mo bi oun iba ti maa ko ohun eelo re ni ijanu ni iwa-mimo ati ni ola. Kii se sise ifekufee gege bi awon Keferi ti ko mo Olorun. Ki enikeni ma se rekoja, ki o ma si se se arakunrin re ninu nnkan naa, nitori Oluwa ni Olugbesan ninu ohun gbogbo nnkan wonyi, gege bi awa ti kilo fun yin tele, ti a si jeri pelu. Nitori Olorun ko pe wa fun iwa eeri, sugbon ni iwa mimo (1 Tesalonika 4:3-7)
EKO
Pansaga ati agbere je iwa ese, Olorun si korira re. Inu Eledaa ko le dun si awon ti nsee. Bibeli wi pe “tabi eyin ko mo pe ara yin ni tempili Emi Mimo, ti nbe ninu yin, ti eyin ti gba lowo Olorun? Eyin kii si se ti ara yin (1 Corinti 6:19) nitori naa, gbogbo omo Olorun gbudo ni ikola aya, ki o ba le ri eto re gba.
ADURA
Olorun Olufe, mo bebe fun gbogboese ifekufe ti mo ti se, mo mo wipe ago ara mi ni tempili Emi Mimo. Mo pinu lati sa fun pansaga ati agbere. Lati akoko yi, emi yio maa gbe igbe aye iwa mimo, emi o si duro sin sin ni idapo pelu re. Jowo fun mi ni agbara ati ore ofe lati mu iduro mi pelu re se dede titi dopin. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
