OWU JIJE
Oba Saulu pa ogorin ati marun/marun din ni aadorun alufaa olorun nitori Dafidi. O pase ki won pa gbogbo ilu ti alufaa wonyi ngbe. Adaniloro oba yi so wipe, awon alufaa olorun wonyi wa ni ifowosowopo pelu Dafidi lati se atako. Bibeli fi ye wa bi oba saulu se gbogun ti awon omo olorun. Saulu si wi fun un pe, eese ti eyin fi n dimolu si mi, iwo ati omo Jese, ti iwo fi fun un ni akara, ati ida, ati ti iwo fi beere fun un lodo olorun, ki oun ki o le dide si mi, lati ba de mi; bi o ti ri lonii. Ahimeleki si da oba lohun, o si wipe, tani oluwa re ti o se eniyan re ninu gbogbo awon aranse bi Dafidi, eni tii se ana oba eni ti o ngbe tire, ti o si ni ola ni ile re? Oni ni emi o sese maa beere ni owo olorun fun un bi? Ki eyi nni jinna si mi, ki oba ki o ma se ka nkankan si iranse re lorun, tabi si gbogbo idile baba mi nitori pe iranse re ko mo nkan ninu gbogbo nkan yii, die tabi pupo. Oba si wipe, Ahimeleki, kiku ni iwo o ku, iwo ati gbogbo idile baba re
(1Samueli 22: 13-16).
EKO
Owu jije buru, omo olorun ko gbudo gba emi owu jije ki o gba aye won. Emi buburu ko se enikeni ni anfani, dipo nse lo ma parun, enikeni ti o ba faye gbaa. Enikeni ti o ba ri ifara han emi owu jije, ki o lakaka lati tii jade lesekese. A nilo agbara olorun lati le bori owu jije, gbogbo omo olorun nilati gbadura fun agbara naa. Kii se pe awon omo olorun yi o gbadura sugbon ki a ma se bo sinu idanwo owu jije. A le ko ara wa lati bori irora, ofo, ayo ati aseyori pelu awon eniyan wa. A ko ni lati se ilodi si ife elomiran, boya ebi wa, tabi awon ore, tabi aladugbo.
Ni oro kan, o ye ki a yo pelu alayo, ki a si kedun pelu eni ti o ba nsofo. Ki olorun fun wa ni emi to dara ti orun yi o so rere nipa re.
ADURA
Olorun olufe, jowo ran mi lowo lati le fe awon eniyan tokan tokan. Je ki inu mi dun nigba ti won ba nyayo, ki emi si se kun aseyori awon eniyan. Ma se je ki nje okunfa isubu awon eniyan, sugbon se mi ni oluranlowo igbega won. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
