ONIGBAGBO GBODO GBA IBAWI
Jeremiah wonu wahala nipa siso asotele ero Olorun, ijoba ati olori elesi Juda muu, nitori okilo fun won lati jawo ninu sise eyi ti o buru tabi ki won gba ere re. Bibeli wipe ‘O si se nigba ti Jeremiah pari gbogbo oro ti Olorun pase fun un lati so fun gbogbo eniyan, nigba naa ni awon alufaa ati awon wolii ati gbogbo eniyan di mu wipe, kiku ni iwo o ku. Eese ti iwo so asotele ni oruko Oluwa wipe, ile yi yoo dabi Silo ati ilu yii yoo di ahoro laini olugbe? Gbogbo eniyan kojo po ti Jeremiah ni ile Oluwa.
(Jeremiah 26:8-9)
EKO
Awon alaisooto eniyan ko fa idojuko, won gba lati wa ninu ese won. Awon olotito eniyan nfe ibawi nipa ti Olorun, ki won ba le se aseyori. Awon ti won ko fe ibawi ni gbangba, ti won ko si ni fe lati se atunse ni a pe ni agberaga. Oju ara won ni won fi nwo ohun gbogbo, won o si wo ese lati te ife okan won. Olorun korira igberaga, o korira awon ti ko ni wo ese pelu oju mejeeji fun atunse, ki won si se atunse ti o ba ye. Awon omo Olorun nilati sora, ki won mase subu sinu eyi, a ko ni lati se okan wa le si ese, sugbon ki a gba atunse, ki a si gba lati se atunse nigba ti a ba dese. A nilati gba atunse Olorun ati ofin re ninu Bibeli. Ki a si gboran nigba ti won ba bawa wi ni ona miran, boya nipa wiwaasu tabi ibawi nigbangba, Jehofa yi o bu ola fun wa ti a ba se ibawi ni owo re, ibukun atokewa re yi o je tiwa, bi a ba le huwa bi aguntan lowo oludari re.
ADURA
Olorun olufe, jowo se mi ni olotito ati onirele ti o see gbeke le ni owo re, se mi ni eni ti a le bawi. Jeki eran ara mi le gba ibawi ninu Bibeli, ki emi si gboran si ase re ti o le wa lona miran, ki emi le se rere ni aye, ki nsi de orun rere. Jowo fun mi ni ore-ofe lati maa sin o gege bi ireti re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
