OLORUN NI ASIRI ASEYORI
Agba yannu adura ran awon ijo isaju lowo lati le duro, ti won si saseyori leke inunibini lati ita ati ipinya lati inu ile, agba yanju adura ran kristieni akoko lowo lati se aseyori ati lati le de awon agbegbe miran ni agbaye. Emi-Mimo ndari awon eniyan mimo, o si nko won ni igbese ti o kan lati gbe, fun apere, Emi-Mimo dari awon eniyan mimo lati ran(Paulu) Saulu ati Banaba jade ni agbegbe won lati waasu ihinrere. Won gboran, Paulu se isoji ita gbangba nibi ti kii se ile Isreali, gbogbo eniyan ni agbaye ti bere si ri abajade ise won titi di oni. Eri iyebiye ni a le to lo sinu iwe mimo
Awon Aposteli 13:2-3 (Bi won si ti njosin fun Oluwa, ti won si ngbaawe Emi-Mimo wipe, E ya Barnaba ati Saulu soto fun mi fun ise ti mo ti pe won si, nigba ti won si ti gbaawe ti won si ti gbadura, ti won si ti gbe owo le won, won si ran won lo.
EKO
Enikeni tabi akojopo eniyan ti o ba gbadura, ti o si yan layo gbigboran si ofin Olorun, yi o se rere pelu idaniloju ti o peye. Olorun lo ni asiri aseyori, O si nfihan awon omo re ti o ba gboran, ko si eni ti o le mo titobi re, yi o je iyalenu bi Olorun yi o se bukun awon omo ti o ba gboran, yi o ni aseyori ni aye, ko si ipenija ti o le ye ileri Olorun lori wa.
ADURA
Olorun olufe, jowo ran mi lowo ki nle wa oju re ninu adura, ki nsi gboran si ase re, ki emi le se rere. Je ki ngbagbo pe iwo ni oludari aye mi ati pe ohunkohun ko le ye ipinu re lori aye mi, je ki nfeti bale gbo o, lotito gboran si ase re, ki nle se aseyori pelu eri ti o duro. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
