OLORUN YIO MU O LAJA
A le ri iyanu Olorun ninu igbe aye Dafidi, o jade wa lati eya ti o kere, lati ilu kekere, ko si ni ipo kan Pataki laarin awon arakunrin re, sibe Olorun ni eto (ipinu) ti o yato fun un. Eledaa gbe Dafidi dide lati ipo ti o kere pupo lo si ipo to ga gidi. O mu ki o bori ogun aye re, o si dee ni ade, gege bi Oba Israeli ti o ye. Bibeli so wipe Bee ni Dafidi nga, o si npo sii, nitori ti Oluwa awon Omo Ogun wa pelu re (1 Kronika 11:9)
EKO
Olorun kii paro, ko si ni yi ipo re pada si awon Omo re. Yio se ohunkohun ti o ba seleri fun won, ni abe akoso bo ti wu ki o ri. Ogun aye lee gbona girigiri, ki nkan nira gidigidi, sugbon awon Omo Olorun yio ni isegun nikehin. Niwon igba ti Olorun ko ni gbonjege ileri re, ko ni yi okan re pada, yio duro ti oro re, lati rii pe awon omo re npin eri won.
ADURA
Olorun Olufe, jowo jewo ileri didara re lori aye mi. Mo mo pe ileri re daju, won yio si wa si imuse. Nitori naa, pase sinu aye mi, alafia/ilera pipe, emi gigun ati aseyori. Ran mi lowo lati maa je igbadun didara re lati akoko yi lo ati ni gbogbo igba. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
