MASE JE OKUTA TI YIO GBE AWON ONIGBAGBO OMIRAN SUBU
Aposteli Paulu gba awon Kristeni niyanju, ki won jina si ohunkohun ti o le fa aigbora eni sodi, ti o si le mu isinaba awon eniyan. Paulu fi ounje se apere, o si wipe ‘Nitori naa, bi ounje ba mu arakunrin mi kose, emi ki yio si je eran mo titi lae, ki emi ma baa mu arakunrin mi kose (1 Korinti 8:13)
EKO
Gbogbo Kristeni lo ye ki a sora bi a ti nsa ere ije ti Emi ki a ma je idanwo fun awon ara wa lati dese si Olorun. Bi a ti mo pe gbogbo wa ko ni odiwon igbagbo kan naa. Awon kan ni igbagbo ti o le, beeni awon kan nba igbagbo won jijakadi. Beni awon omode ninu igbagbo nwo awon kan ni awokose pe won ju won lo nipa ti Emi. Iru alawose (Omo ehin) wonyi le te si ibi ti adari won ba dari si. Nitorinaa ki enikokan wa sora bi a tin se igbagbo wa. Gbogbo Kristeni b’oya odo tabi agbalagba ni lati sora bi a tin lo ominira wa ninu Olorun. Ki awa Kristeni lo igba aye wa bi yio ti gbe ogo Olorun ga, niwon bi awon eniyan Pataki ki a mo, ati ti a ko mo, le maa tele wa.
ADURA
Olorun Olufe, jowo se mi ni Kristeni to dara, ki emi je apere rere ti awon eniyan yio maa tele. Mase mi ni okuta idena fun ore-ofe igbala fun elomiran. Je ki nfi suuru ati otito sin o, ki awon eniyan rii, ki won si yin oruko mimore logo. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
