OLORUN WA KUN FUN IYANU
Olorun se opolopo ise iyanu lati owo Woli Elisa nigba aye re. Nipa ase oku eniyan di alaye, aake fo soke lati isale odo, iyan ojo pipe wa si opin ni oru ojo kan. Eyi ti o ga ju ninu ise iyanu ti Elisa ni a fe fenu ba. Oku egigun re so oku ara elomiran di alaye. Bibeli salaye bi a ti koo pe Elisa si ku, won si sin-in, Egbe awon ara Moabu si gbe ogun waile naa ni amodun, o si se, bi won ti nsinku okunrin kan, si kiyesii, won ri egbe-kan, won si ju okunrin naa sinu isa-oku Elisa, nigbati a si soo sile, ti okunrin naa fi ara kan egungun Elisa, o si soji o si dide duro ni ese re. (2 Awon Oba 13:20-21)
EKO
Olorun kun fun iyanu, yi o si se ohun nla fun awon omo re. Olorun yi o bukun awon omo re, yio si lowon lati bukun awon eniyan miran pelu. Enikeni to ba fi tokan tokan sin Olorun ti o si gboran si ase re, apere re yi o kun fun eri. Ko ni si idiwo fun iru eni bee lati ni eri, nitori naa gbogbo eniyan nilati mo wipe, o ni ere pupo lati sin Olorun. Enikeni to o ba mokan le lati ni idapo to peye pelu Olorun, ko ni kabamo, labe akoso bo ti wu ki o ri.
ADURA
Olorun Olufe, mo mo wipe iwo yio se ise iyanu nla fun enikeni ti o ba fi igbagbo sin o, ti o si gboran si ase re. Nitori naa mo fe gboran si o, ki nsi ni idapo to dara pelu re. Jowo ran mi lowo lati le ko gbogbo iwa ilodi si Olorun, ki emi le gbadun re jinle. Je ki nfe, kin sin o pelu. Si ka mi ye fun opo ibukun re ni aye yi ati ni orun, ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
