OLORUN KORIRA IWABUBURU
Olorun korira iwa buburu, o si ro awon oluse buburu ki won ronupiwada kuro ninu ona ibi won. Jehofa yi o bukun awon ti o ba ronupiwada, sugbon yi o buru nikehin fun awon ti o ba ko lati ronupiwada. Olorun wipe egbe ni fun awon ti ngbimo aisedede ti nsise ibi lori akete won, nigba ti ojumo mo won n see, nitoripe o wa ni agbara owo won, won si nse ojukokoro oko, won si nfi ipa gba a ati ile, won a si mu won lo won si ni eniyan lara ati ile re, ani eniyan ati ini re.
(Mika 2:1-2)
EKO
Olorun ko rin ni ona kan naa pelu eniyan buburu. O korira iwa buburu, awon aninilara ti won unlo ipo won lati re ni je unbe labe anu Oluwa lati gba idajo, ayafi bi won ba ronupiwada. Nipa iwabuburu ironupiwada ni ohun ti o tona, niwon bi Jehofa se mo ohun gbogbo ti o si ri ohungbogbo, yi o se idajo otito re lori awon oluse buburu ni akoko to ba ye. Ninu awon ohun ti Olorun unfe ti yi o fa ibukun re ni sise rere, idajo otitio, ikaanu, enikeni ti o ba unreti ibukun nilati maa se itoju awon elomiran ki o si bowo fun won, iru eni bee yi o wa ni iduro pipe pelu Olorun.
ADURA
Olorun olufe, jowo je kin le toju awon elomiran pelu daradara ati pelu ife. Mase je ki agbara ipo ti mo ba wa bomi loju, sugbon se mi ni asoju ohun ti o dara, jowo dari awon ese ti mo ti da sehin ki o fi ife gba mi pada. Romi ni agbara ki nle fi aanu ore-ofe re huwa si awon eniyan, ki oruko re di gbigbe ga ni gbogbo igba. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
