OGUNREGE IDABOBO NWA LATI OLORUN
Ko si eni ti o le fowo soya fun abo to daju, yato si Olorun. Ko nii fi nse iru abo ti enikeni ba se, ko pe, ko si le gbogun ti gbogbo ewu tabi ijamba ti a ko fe. Bibeli tile wipe ko si Oba kan ti a ti owo opo ogun gba sile, ko si alagbara kan ti a fi agbara pupo gba sile. Ohun asan ni esin fun igbala, bee ni ki yio fi agbara nla re gbani sile. (Orin Dafidi 33:16-17)
EKO
Abo to peye wa lati odo Olorun nikan, awon onigbagbo ninu Jesu Kristi ni ipin ninu re. Olorun feran awon omo re, yio si fi won si abe abo iso oju re. Awon ti o ba fi eran ara se igbekele yio gba ijakule, nitori ogbon eniyan ni odiwon. Ko si eni ti o le pese abo to peye. (Ipese abo nipa owo eniyan ko daju) Ipese abo to peye lati odo Olorun si awon omo re, yio wa titi aye. Lati ye fun abo Olorun, iru eni be yio ti jewo Jesu Kristi ni Oluwa, ki o si ni iberu Olorun ni gbogbo ona.
ADURA
Olorun Olufe, jowo mo fe abo ti o daju fun aye mi. Nitori naa, mo jewo ese mi, mo si ronupiwada kuro ninu won. Mo si jewo omo re Jesu Kristi bi Oluwa, mo si gbaa ni Olugbala mi. Jowo fi ese mi mule bi omo re tooto, ti yio maa je igbadun abo re to doju ati awon anfani miran. Ni Pataki, ko oruko mi sinu iwe iye, ki won, le gba mi sinu ijoba orun re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
