OFIN IDAMEWA JE AIMASE FUN ONIGBAGBO
Olọrun jẹ ko di mimọ fun awọn. Ọmọ Israeli idi Pataki sisan idamẹwa wọn ni kete ti wọn ba de ile ileri. Nigba ti iwọ ba da idamẹwa asunkun rẹ tan ni Ọdun kẹta, ti se Ọdun idamẹwa, ti iwọ si fi fun. Ọmo Lefi, alejo, alaini-baba, ati opo, ki wọn ki o maa jẹ ni enu-bode rẹ ki wọn si yò. Nigba naa ni ki iwọ ki o wi niwaju Oluwa Olọrun rẹ pe, ẹmi ti mu ohun mimọ kuro ninu ile mi, mo si ti fi wọn fun Ọmo Lefi, ati fun alejo, ati fun alaini-baba, ati fun opo, gẹge bi gbogbo aṣẹ re ti iwo ti pa fun mi, ẹmi ko re aṣẹ re kọja bẹẹ ni ẹmi gbagbe wọn (Deutaronomi 26: 12-13).
EKO
O ṣe Pataki ki gbogbo Onigbagbọ mọ Pataki ati ofin ti o rọ mọ sisan idamẹwa. Olọrun nfẹ ki awọn Ọmo rẹ san idamẹwa (10%) ere (IDAMEWA) fun ipologo ihinrere, pipese ini awọn iranṣe Olọrun, pipese fun awọn alaini. Onigbagbọ ni lati mọpe, Olọrun ko fi sisan idamẹwa ṣere, eto Olọrun ni. Olọrun fun wa ni anfani iyoku (90%) ipa aadorun ere wa, o nira fun opo awọn Onigbagbọ lati fun Olọrun ni tire. Won nfẹ gbogbo ọgọrun (100%) fun ilo ara wọn ni kan, idi ni yi ti Olọrun ṣe pe wọn ni ole (Malaki 3:8-10). Olọrun ti o ṣeto idamẹwa ko ni fowọ pa awọn Ọmo rẹ ti ko pa ofin rẹ yi mọ. Gbogbo awọn ti o kuna lati maa san idamẹwa ni a ka si ẹni ti ko pe ni iwa, ẹsan si wa fun iru eniyan ḅe. Ere bi aitete ri idahun si adura, tabi pipadanu anfani. Awọn Onigbagbọ ti o bowọ fun Olọrun nipa sisan idamẹwa ẉon yi o ri opọlọpọ ibukun gba. Jehofa yi o fun awọn olotito Onigbagbọ ni anfani lati jẹ olotito si.
ADURA
Olọrun, jọwo ran mi lọwo ki nle jẹ olotitọ ni sisan idamẹwa mi. o to gẹẹ ni didena ibukun mi nipa aisootọ sisan idamẹwa mi, Ẹ dari ji mi nipa aijolootọ atẹhinwa, jẹ kin bẹrẹ si san bo ti ye, ki nle ri ibukun rẹ gba. Jọwo je ki ilẹkun anfani si silẹ fun mi ni gbogbo ayika mi, ki emi di ẹni ibukun ki nsi le wa siwaju rẹ pẹlu ‘Idamẹwa ati ore ti o sanra’ Je ki ẹri didara rẹ kun enu mi. ni orukọ Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
