O GBODO GBA IJOBA EMI MIMO LAYE NINU RE
A ro Kristeni ki won je olotito ninu idapo won pelu Olorun, ki won si je apere ti o dara fun awon eniyan. Bibeli wipe Ni akotan ara, ohunkohun ti se ooto, ohunkohun ti se owo, ohunkohun ti se tito, ohunkohun tii se mimo, ohunkohun tii se fife, ohunkohun ti o ni iroyin rere, bi iwa tito kan ba wa, bi iyin kan ba si wa, e maa gba nnkan wonyii ro. (Filippi 4:8)
EKO
Olorun nfe ki awon omo re mu iduro sin sin won, ki won je ki idapo won ki o se deede pelu re. Won ni lati maa gbe igbe aye ti awon elomiran yio fi se ari kose. Sugbon ko si eni to le se eyi laisi iranlowo Emi Mimo. O wa se Pataki ki gbogbo Kristeni ni ojoojumo maa bebe fun kikun fun Emi Mimo, ki won ba le maa tee lorun.
ADURA
Olorun Olufe, mo nilo iranlowo Emi Mimo ki emi le je Kristeni ti o dara. Mo rii wipe, emi ko ni okun, emi ko si le ye fun ibere re pelu agbara eran ara, nitori naa, mo beere ki o fun mi ni agbara Emi Mimo. Fun mi ni ifami ororo yan ti ore-ofe lati le sin O bo ti ye, ki emi si je apere ti o dara fun awon eniyan lati tele. Lehin gbogbo re, je ki emi gba ade ogo ti kii dibaje ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
