NI IGBAGBO NINU OLORUN
Igbagbo se pataki fun eniyan ati si Olorun. Oun ni opa asopo fun awon mejeeji. Eni ti ko ba ni igbagbo ko lee ni irepo pelu Olorun, bi o ba gbiyanju, Olorun ko ni da iru eni bee lohun. Bibeli wipe ‘Nje igbagbo ni idaniloju ohun to a nreti, ijeri ohun ti a ko ri. Nitori ninu re ni awon alagba ti ni eri rere. Nipa igbagbo ni a mo pe ati da aye nipa oro Olorun, nitori naa kii se ohun to han ni a fi da ohun ti a nri (Heberu 11:1-3)
EKO
Igbagbo ni okunfa iseda, Olorun da ohun gbogbo nipa igbagbo. Eledaa ni igbagbo ninu ara re, nipa dida ohun gbogbo lati inu airi. Nipa agbara oro, o da aye ati ohun gbogbo ti mbe ninu re. Olorun wipe…… (Genesisi) ohunkohun ti o ba wi, nwa si imuse. Niwon bi Olorun ti O da wa ti gba ara re gbo ti o dara. Eda ni lati ni igbagbo ninu Eledaa re, eniyan ni lati gba pe Olorun wa, ki won gbagbo ninu agbara re, ki ipeti won si wa lodo re, pelu idaniloju pe yio di mimu se. Enikeni ti o ba nreti ifara han agbara nla Emi Olorun ni lati gbagbo pe Olorun lee se ohun gbogbo, ki iru eni bee maa jewo igbagbo ninu re.
ADURA
Olorun Olufe jowo ran mi lowo lati ni igbagbo ninu re, fun mi ni okun lati le jewo igbagbo ati igbekele mi si O ni gbogbo ona aye mi. Je ki Emi Mimo re ro mi ni agbara lati maa kede ileri ese bibeli sinu aye mi. Je ki oro ijeri lati enu mi, ki o je eyi ti o dara, ki emi sigbe igbe aye asegun nile aye. Jowo je ki emi je eso igbagbo, si je ki eri mi duro laelae. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere, Amin.
