FE LATI YI PADA SI ONA TITUN
Olorun se ikilo fun awon Juda ti o ku ni ile won ki won mase wa iranwo lo si Egipti, a o je won niya bi won ba se bee. Won yio se rere bi won ba duro ni ile Juda, Olorun soro lati enu Jeremiah o wipe, ‘Bi eyin o ba gbe ile yi looto, nigba naa ni emi o gbe yin ro, emi ki yio si fa yin lule, emi o si gbin yin, emi ki yio si fa yin tu, nitori emi yi okan pada ni ti ibi ti emi ti se si yin. E maa beru Oba Babeli, eni ti eyin n beru, mase beru re, ni Oluwa wi nitori emi wa pelu yin lati ran yin lowo, ati lati gba yin ni owo re. Emi o si fi aanu han si yin, ki o si mu ki eyin pada si ile yin. Sugbon bi eyin ba wipe, awa ki yio gbe ile yi, ti eyin ko si gba ohun Oluwa Olorun yin gbo wipe bee ko, sugbon awa fe lo si ile Egipti, nibi ti awa ki yio ri ogun kogun, ti a ki o si gbe iro fere, ti ebi ounje ko ni I pa wa, nibe ni awa o si maa gbe. Nje nisisinyi, nitori naa e gbe oro Oluwa, eyin yooku Juda, bayi ni Oluwa awon Omo Ogun Israeli, wipe, bi e ba gbe oju yin patapata le ati lo si Egipti, bi eyin ba lo lati se atipo nibe, yio si se, idati eyin beru, yio si le yin ba ni ile Egipiti, ati iyan ti eyin beru yio tele yin girigiri nibe ni Egipti, nibe ni eyin o si ku (Jeremiah 42:10-16).
EKO
Olorun nfe ki awon omo re ni iwa irele, ki won si gba atunse pelu igbagbo ti o dara. Oye ki a tele ofin, kia se atunse nigba ti a ba se asise. Ko ye ki awa omo Olorun gberaga nigba ti a ba se asise, sugbon ki a kabamo, ki a si to Olorun pada wa. Olorun oloore ofe to ga ju lo, o ni ife ninu ironupiwada wa. O nfe ri wa, ki a maa rin ninu ilana re, ki o ba le ro ojo didara re le wa lori. Ti a ba le te Olorun lorun, yio bukun wa ni akoko to ba ya, ninu ola ni a o gbe asia wa soke.
ADURA
Olorun Olufe jowo fun mi ni okan irele, ti emi yio fi gba asise mi ti emi o si se atunse to ye. Fun mi ni okun lati se ofin re pelu emi irele, ki emi ki o lee se rere ni ile alaaye. Je ki emi wa ni abe iso oju re, ki emi si ye fun ibukun re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere, Amin.
