MA SE FARA JIN FUN IDANWO
Oba Saulu ba ara re laarin okuta ati ibi to le, awon ota re ti po niye ju tire pee nija, eru baa won omo ogun re won bere si nsalo ni kokan. Eyi ti o tun buru ni pe Wolii Samueli ti o ye ki o ru ebo ibile saaju ojo ogun, ko ti fara han titi di ojo keje. Oba Saulu wa ninu idamu ati wahala, sugbon oni lati se nkankan, igbese to gbe ko so eso to dara. O se irubo to je pe Wolii Samueli lo to si, ni kete ti o pari irubo tan ni Wolii Samueli de abajade ati ehin re ko dara. Samueli wipe ‘Samueli si wi fun Saulu pe, iwo ko hu iwa ologbon, iwo ko pa ofin Oluwa Olorun re mo, ti oun ti pa ni ase fun o. nitori nisisinyi ni Oluwa ibafi idi ijoba re kale lori Isreali lae lae, sugbon nisinsinyi ijoba re ki yo duro pe, Oluwa ti wa fun ara re okunrin ti o wuu ni okan re, Oluwa pase fun un ki o se olori fun awon eniyan re, nitori pe iwo ko pa ase ti Oluwa fi fun o mo. (Samueli kini 13:13-14).
EKO
Yi o gba ore-ofe ati anu Olorun ki a to la bori idanwo, bakan naa yi o gba aanu Olorun lati le yan eyi ti o dara bi a ba unla igba inilara koja. Olorun yi o ran awon omo re ti o ba kepee fun iranlowo. Yi o ran won lowo lati gbe igbese toto lakoko ti won nilo re, yi o si ri daju pe won ni isegun lori igbenija won. Nitorina omo Olorun ni lati ko bi a se nkepe Olorun ohunkohun tabi ipokipo to le de ba won, kosi ohun ti o kere lati fi sinu adura, ko si Kristieni ti o ni lati ni ero keji ti o baunkepe Olorun fun iranlowo.
ADURA
Olorun olufe, jowo fun mi ni ore-ofe lati ke pe o nigba ti mo ba wa ninu isoro. Dari mi ki nle yan eyi ti o dara nigba iporuru okan, si ran mi lowo lati tele ilana re ki nba le ni ireti ikehin. Je ki o maa dara fun mi ni gbogbo igba, si je ki Satani gba itiju lori aye mi. ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
