MA SE DUNNU NIGBATI ONIGBAGBO BA KOSE PADASEHIN
Bibeli salaye idi imupada sipo awon onigbagbo ti o ti subu (apehinda) a ti koo pe Ara bi a tile mu eniyan ninu isubu kan, ki eyin ti se ti Emi ki o mu iru eni bee bo sipo ni emi iwa tutu, ki iwo funrare maa kiye sara, ki a ma baa dan iwo naa wo pelu. E maa ru eru omonikeji yin, ki e si fi bee mu ofin Kristi se. (Galatia 6:1-2)
EKO
O maa ndun Olorun. Okan re si maa nbaje nigbati onigbagbo ba subu ninu ore-ofe. Eledaa yio sa gbogbo ipa re lati mu iru eniyan be pada sipo. A ro Kristeni lati je asoju Kristi, ki a si sa gbogbo ipa wa lati mu awon apehinda pada wa sinu igbagbo. A je asoju Kristi, a nilati gbe awon Kristeni to subu dide. Satani le gbiyanju lati tan onigbagbo je, nipa kikuna mimu arakunrin to subu pada bo sipo. Kristeni ni lati jawo ninu kikegan arakunrin re. Ojuse wa ni lati gbadura, gba won niyanju, ki a si sunmo won titi won o fi pada sinu igbagbo. Olorun yio lo okan ikaanu wa bi ohun elo lati ran awon apehinda onigbagbo lowo lati dide, ki won si ni okun ninu Oluwa. Eledaa yio bukun onigbagbo ti o baa nran awon elomiran lowo.
ADURA
Jesu Kristi olufe, se mi ni ohun elo, ti yio mu ki awon apehinda pada sipo. Fun mi ni agbara lati le gbadura, se itoju won titi won o fi pada sipore. Mo sin lo akoko yi lati gbadura fun awon to subu so ife akoko nu, ki won pada sipo. Mo gbadura ki Olorun alagbara pe won sinu ijosin tooto. Mo gbadura ki Olorun da ina si okan won, ki won le tesiwaju lati maa sin Olorun ninu emi ati otito. Ki agbara Olorun wa sori awon eni mimo ki won duro sinsin titi ti igba ti Kristi yio fara han ni ori ile aye. Ki Emi Mimo wonu awon arakunrin ati arabirin ti o nrewesi ninu ife otito Olorun. Je ki awon arakunrin ati arabinrin ti o je olotito maa tesiwaju titi dopin, ki gbogbo wa le ke Hosana ki a si korin isegun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
