LILO ASE TIN BE NINU ORUKO OLORUN
Goliati dari awon Filistini lati hale mo awon Isreali fun ogoji ojo, Goliati je omiran ti o singbole, akikanju okunrin ogun ti awon omo Isreali ko le doju koo. Awon jagun jagun alaigbagbo gegun fun Isreali won si gan Olorun won, ko si jagun jagun Isreali kan ti o ni igboya lati doju koo titi kan oba Saulu. Sugbon omode kunrin kan (O kere lati koo mo awon jagun jagun) ti a unpe oruko re ni Dafidi ni igboya lati dide ti o si dojuko ipenija Goliati si oju ija. Dafidi je eni oto ti o pa Keferi lenu mo ti o gan Olorun ati awon jagun jagun re. omode kunrin na so pe ‘Kini a o se fun okunrin naa ti o ba pa Filistini yi, ti o si mu egan naa kuro ni ara Isreali? Ta ni alaikola Filistini yi se, ti yoo fi ma gan Olorun alaaye?
(Samueli kinni 17:26)
Sugbon Goliati fi Dafidi se yeye, o si fi re pelu orisa re. dafidi si daa lohun pelu awon oro die yi ki ijagun to bere, idahun re niyi iwo mu ida, ati oko, lati wa to mi wa sugbon emi to o wa ni oruko Oluwa awon omo-ogun, Olorun ogun Isreali ti iwo fi gan. Dafidi si pa Goliati soju ogun naa, o si ri pe gbogbo ogo je ti Olorun alaaye ti Isreali. (Samueli kinni 17:45).
EKO
Goliati je asoju Satani ti o hale lojoojumo mo awon omo Isreali fun ogoji ojo titi igbati Olorun ro Dafidi ni agbara ti o si paa lenu mo patapata (Samueli kini 17:26) Satani si ni opolopo Goliati ti o nlo lati maa hale mo awon omo Olorun a si ni lati pa won lenu mo. Ipa ono ti Dafidi lo lati pa Goliati ti akoko lenu mo naa lo ye ki a lo lati pa Goliati ti o ba le fara han ninu igbe aye kristieni wa. Ohun ija kristieni si iran Goliati, a ko ni lati wo pelu oju ti ara sugbon a nilati woo niti emi, onigbagbo ni lati lo adura lati segun Satani ni gbogbo igbiyanju re. bi o tile le doju ko wa ni ona ti o po, a o segun won nipase adura igbagbo. Onigbagbo ni lati mo pe Satani ko ni agbara lori adura, Olorun ni eyi. Ota yi o sa nigba ti kristieni ba daruko Jesu Kristi ninu adura won, gbogbo omo Olorun nilati lo igbagbo won ki won si lo agbara ti Olorun fun won lati bori Satani.
Fun apere
* Eni ti o ni igbenija nipa igbeyawo le gbadura pe ‘Mo pase fun o Satani, jade kuro ninu igbeyawo mi ni oruko Jesu Kristi, igbeyawo mi je ti Olorun, mo si pinu lati gbadun re.
* Eni ti o ni igbenija nipa ti Alafia ara le so wipe, mo pase fun Satani ki o yowo ninu ago ara mi ni oruko Jesu. Mo gba Alafia ati iwosan pipe, mo si gba pipe ara mi nipase eje Jesu Kristi, mo kede iwosan mi looni, lola ati titi lae ni oruko Jesu Kristi.
* Eni ti o se alaini ohun ini le so wipe, mo ba Satani wi mo si pase ki o yowo idoti re kuro ninu ini mi. Olorun je oloro, emi na je oloro, mo pa aini run ninu aye mi, mo kede ara mi gegebi oloro. Mo gba isegun pipe lori aini looni ati titi aye ni oruko Jesu Kristi. Amin
ADURA
Jesu Kristi olufe jowo je kin le lo ase ti nbe ninu oruko re, ro mi ni agbara lati bori ami ati ifarahan Goliati ninu aye mi. fi ifami ororo Emi Mimi yan mi kin le lo igbagbo mi lona ti yio se ijoba re ni anfani, ti yio si bukun aye mi, ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin .
