LATI TE OLORUN LORUN A NILO EMI MIMO
Awon omo Olorun gbodo ko ifekufe ara sile lati rin ni abe itonisona Emi-Mimo. Bibeli sowipe ‘Sugbon mo n so fun yin pe ki e je ki emi maa dari igbe aye yin, ti e baa nse bee, e ko ni mu ifekufe ara se’ (Galatia 5:16). Awon ifekufe ara ti awon Onigbagbo gbodo sa fun ni Bibeli daruko bayii ’19 - 21. Awon ise ara farahan gbangba, awon ni agbere, iwa eri, wobia, iborisa, oso, odi-yiyan, ija, owu jije, irunu, okanjuwa, iyapa, rikisi, inu buruku, imutipara, ariya awon omuti ati iru nnkan bee. Ohun ti mo ti so fun yin tele ni mo tun so fun yin, pe awon ti o n se iru nnkan bee ko ni jogun ijoba Olorun.’
EKO
Igbagbo ninu Jesu Kristi maa n pese aaye fun eniyanlati gbe igbe aye irorun, sugbon sibesibe Onigbagbo gbodo ni oye wipe irin igbagbo Kristieni nilo isera eni. Gbogbo Onigbagbo patapata ni o gbodo le se ara re lati ko iwa ese sile, nkan wonyi ti Oluwa korira eyi tunmo si wipe, a gbodo pinu lati gbe igbese pe a ko ni te ifekufe ara. Aseda yio san esan rere fun wa ti a ba se ife re ni igbe iwa mimo, ki a to le te Olorun lorun Onigbagbo gbodo se tan lati gba Emi-Mimo laye lati dari aye wa. Emi Olorun ni yio ran wa lowo lati lee so eso to lere fun ijoba re. Awon eso emi ni iwe mimo so bayii . ’22. Sugbon eso ti emi ni ife, ayo, alaafia, suuru, aanu, ise rere, isotito, iwa pele, isera eni. Ko si ofin kan ti o lodi si iru nnkan bawonyi.’ (Galatia 5: 22-23)
ADURA
Olorun mi, jowo je ki Emi-Mimo re ko gba akoso aye mi, ki mba le wu o nipase ise oojo mi. Ran mi lowo lati pa gbogbo ise ara ki mba le ni opolopo aaye fun Emi re lati joba, jowo ran mi lowo lati so eso pupo si ijoba re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo be o. amin.
