ISEGUN DAJU FUN AWON OMO OLORUN
Hamani di ote lati pa Mordekai, bakannaa ni akoko yi ni Olorun pinnu lati gbee ga. Ife Olorun se lori Mordekai, a gbee ga, sugbon ota re Hamani ni oju ti won si paa. (Apa Hamani nitori Mordekai ati awon Juu). Bibeli wipe ni oru naa, oba ko le sun, o si pase pe ki a mu iwe iranti ani irohin awon ojo wa, a si ka won niwaju oba. A si rii pe a ti koo pe Mordekai ti so ti Bigtani, ati Teresi, awon iwefa Oba meji, oluso iloro, awon eni ti nwa ona lati gbe owo le Ahaswerusi Oba. Oba si wipe, iyin ati ola wo ni a fi fun Mordekai nitori eyi? Nigba naa ni awon omo-odo Oba tin se iranse fun un wipe, a ko se nnkankan fun un. Oba si wipe, ta ni nbe ni agbala? Hamani si ti de agbala akookan ile Oba, lati ba Oba soo lati so Mordekai ro sori igi giga ti o ti ri fun un. (O seni laanu pe, nkan yi yi pada sori Hamani).
Hamani wipe ki a si fi ewu ati esin yii le owo okan ninu awon ijoye Oba ti o lolajulo, ki won fi se oso fun okunri naa, eni ti inu Oba dun si lati bu olafun, ki o si mu un gesin la igboro ilu, ki o si maa kigbe niwaju re pe, bayii ni a o se fun okunrin naa, eniti inu Oba dun si lati bu ola fun. Nigba naa ni Oba wi fun Hamani pe, yara Kankan, mu ewu ati esin naa, bi iwo ti wi, ki o si se bee gege fun Mordekai, ara Juda nni, ti n jokoo ni enu ona ile oba. Ohunkohun ko gbodo ye ninu ohun ti iwo ti so. (Esteri 6:1-4, 6:9-10)
EKO
Abo Olorun lori awon omo re ko ni ye labe ohunkohun ti won le maa la koja. Ota awon omo Olorun ni oju yi o ti. Oju yi o ti won fun ise ibi won, a o fi won se eleya. Awon omo Olorun yi o wonu isegun ni gbogbo ona. Oju ki yi o ti won ni akoko idojuko. Niwon bi awon omo Olorun ti ngbe ni abe ore-ofe ti emi, a o fi kun agbara won, lati lee mu opolopo iyin fun oruko Olorun. Ni sin sin Olorun, Kristeni ko ni padanu ohunkohun, won yi o maa gbe igbe aye olubori titi laelae. Bibeli wipe ‘Bi olorun ba wa fun wa, tani yoo ko oju ija si wa? (Romu 8:31)
ADURA
Olorun olufe, jowo fun mi ni ore-ofe re lati je olotito omo ki emi maa je anfani ore-ofe ati abo re. Lu awon ota mi bole titi oju yi o fi ti won, ki emi si segun lori won. Je ki didara re maa po sii ninu aye mi, ki emi si maa je anfani re ni ile alaaye. Jowo je ki awon angeli re maa so mi, ki nmaa gbe ni abe iso re titi laelae. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
