IJIHINRERE KO DA LORI IGBA TI O WO
Ijo ti o wa ni Jerusalemu pe idajo boya ki a yonda awon Onigbagbo ti kii se ara Juu ninu asa Juu? Won si fohun sokan pe o se Pataki ki ara ma sin Olorun ni ominira ti emi lai fi ipa mu wa se awon asa eniyan eyi ti o le se idena imugboro ihinrere, awon alagba ijo kowe si Paulu won si wipe ‘Sugbon ni ti won pa ara won mo kuro ninu ohun ti a fi rubo si orisa ati eje ati ohun ilolorunpa ati agbere. (Awon Aposteli 21:25).
EKO
Opolopo fihan pe Kristieni kii se Juu po niye ju awon Kristieni ara Juu, boya Kristieni je Juu tabi beeko, o je ojuse wa lati pa ofin Olorun mo. A nilati kopa ninu awon ojuse ti yio yin Olorun logo, asa wa le mu wa hu awon iwa kan sugbon ki a ma se se asise so won di ofin Olorun. Awon asa eniyan kiise ofin Olorun, nitori naa a nilati wa inu iwe mimo daradara ki a le mo ohun ti Olorun nfe, aseyori wa yio le duro bi a ba mo, ti a si waa ni otito. Olorun yi o se oruko re logo ninu aye awon ti o ba fi towo towo te le.
ADURA
Olorun olufe, mo mo wipe asa eniyan yato si igbe aye iwa mimo odiwon Olorun, nitori naa, gba mi kuro ninu asa ti o le penija iwa mimo re. Je ki nle maa wa inu iwe mimo ki nle maa gbe igbe aye ti o ye. Jowo gba okan mi lowo asise ki emi ma baa gba idojuti ni ikehin ojo. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
