IFE TI KO KIN RO TIRE NIKAN
Rutu gba lati duro ti Naomi (Iya oko re) lehin iku oko re bi o tile je pe Naomi ti darugbo, ti ko si ohun ti o le fun ni mon Rutu ko gbobgo isipe (Ebe) Naomi, o ko lati pada si ilu ile re. O ko o si wipe ‘Ma se romi lati fi o sile tabi pada kuro leyin re, nitori ibi ti iwo ba lo ni emi o lo, ibi ti iwo ba si wo ni emi o wo, awon eniyan re ni yoo si ma se eniyan mi, Olorun re ni yoo si ma se Olorun mi. ibi ti iwo ba ku si ni emi o ku si, nibe ni a o sin mi, ki Oluwa ki o se bee si mi ati ju bee lo pelu, bi ohun kan bi ko se iku ba ya iwo ati emi (Rutu 1:10-17).
EKO
A ro Kristieni ki o ni ife aimotara eni nikan si eniyan gbogbo. A ko ni lati ma wa ere ti ara wa nikan ki a to ran elomiran ti o fe iranlowo wa, ki a to ran won lowo. Olorun mo ona lati san esan fun ise rere wa, yi o si san esan fun awon omo ti kii se amotara eni nikan. Nitori idi eyi, a ni lati si okan wa paya lati ran elomiran lowo, ki a se lono to to, ki Olorun ba le bukun wa.
ADURA
Olorun olufe jowo ran mi lowo, ki nle fihan ife aimotara eni nikan si awon eniyan. Mase je kin ma lepa ebun tabi ere imotara eni nikan, je kinle se itoju eniyan pelu okan ife. Mo mo wipe iwo yio bukun mi bi mo ba se asoju re ni aye yi, ran mi lowo lati le te o lorun. Je kin je asoju ni aye, si je kin ye ni eni ti yio gba ere ti orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
