IBALOPO LONA TI KO TO
Solomoni oba ti o figba kan feran Olorun, ti o si se ijoba lori awon eniyan re pelu ogbon wa je ki obirin gba okan re. Won mu ki o ya kuro nipa ona Olorun, nigba ti ese ibalopo pelu obirin ti bere Solomoni ko se dede pelu Olorun mo, o si se opolopo asise. Bibeli wipe ‘Solomoni oba feran opo ajoji obirin pelu omobirin Farao, awon obirin ara Moabu, ti Amoni, ti Edomu, ti Sidoni ati awon omo Hiti. Awon orile ede ti Oluwa wi fun awon omo Isreali pe, eyin ko gbodo wole to won lo, beni awon ko gbodo wole to yin wa nitooto won o yi yin lokan pada si orisa won. Solomoni fa mo awon wonyi ni ife, o si ni eedegberin obirin awon omo oba ati oodunrun ale, awon aya re si yii lokan pada. O si se nigba ti Solomoni darugbo, awon obirin re yi lokan pada si Olorun miran, okan re ko si se dede pelu Oluwa Olorun re gege bi okan Dafidi baba re.
(Awon Oba kinni 11:1-4)
EKO
Ese ibalopo yi o mu ki okunrin tabi obirin ki o subu tabi jakule, ibalopo lona aito nfi eniyan sinu atimole. Enikeni ti o ban se agbere ko ni ominira sugbon o wa ninu ide ti emi, yi o si ma gbe gege bi eru, ko si eni ti o dese agbere ti yi o lo loofe, iru eni bee yi o ni nnkan ti yi o padanu. Nitori naa enikeni ti o ba fe gbe igbe aye asegun ni aye ni lati fi sile, idapo ti o le fa pansaga tabi agbere, enikeni ti o ba mu ara duro yi o ri ibukun gba lowo Olorun lai gbadura. Enikeni (eni ti o ti se igbeyawo tabi eni ti ko tii se igbeyawo) ti o mu ara duro, ti o si ni idapo ti o dara pelu Olorunyi o je opolopo anfani lati odo Olorun ni aye ati ni orun.
ADURA
Olorun olufe, mo mo wipe ibalopo pelu obirin ajeji je iwa aiwa bi Olorun, o si le mu ki enikeni subu kuro ninu ore-ofe, nitori naa, mo beere jowo ran mi lowo lati lee mu ara duro. Ran mi lowo lati le yeara fun idapo ti o le ba idapo mi pelu re je, jowo je ki nje mimo, ki nsi fi otito sin o, ki emi le je anfani re, ki emi si se rere ni gbogbo ona aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
