GBOKAN LE OLORUN PATAPATA
Judasi iskariotu yonda ara re fun satani lati loo, o si fi Jesu Kristi han pelu ifenu ko enu. A kowe re pe bi o ti nso lowo, kiyesii opo eniyan, ati eni ti a npe ni Judasi, okan ninu awon mejila, o saaju won, o sunmo Jesu lati fi enu koo ni enu. Jesu si wi fun un pe, Judasi, iwo fi ifenukonu fi omo-eniyan han?.
(Luku 22: 47-48).
EKO
Bi alajosepo bi Judasi Iskariotu ba le da Jesu Kristi, tani a lefokan tan tabi gbekele?. (Luku 22: 47-48). O han gbangba pe aye ti a wa yi ni isoro pelu ifokanto. Aye kun fun ikorira ati egan, imotara eni nikan lo gba aye kan lati ibi kan si ikeji sibe awon omo lehin Jesu Kristi si ni ireti ninu aye yi. A ni ife olorun ti o bori ibi. A le gboju wa soke si olorun ati si awon onigbagbo die. A ko fe ki onigbagbo ki o gbara le eniyan patapata, igbekele wa nilati wa ninu olorun ti ko ni alebu tabi abawon. Olorun kii jani kule bi eniyan tile ja wa ku le. Eniyan le jawa kule, sugbon olorun ko ni jawa kule.
ADURA
Olorun olufe, jowo ran mi lowo lati gbeke le o patapata. Ran mi lowo lati fe ati lati gbekele eniyan, sugbon je ki gbogbo igbekele mi wa ninu yin. Je kin le gbekele o, gbadura, ki nsi gboju soke fun gbogbo ini mi. Mo mo, mo si gbagbo pe, iwo yi o ran eni ti yio tan aini mi ni gbogbo igba. Je ki gbogbo igbekele mi ki o wa ninu re ni gbogbo igba, ki nle gbe igbe aye aseyori ati alayo ninu aye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
