GBE OLORUN GA FUN ISE IYANU RE
Ise ami ati iyanu Olorun ko se nsalaye. Onisamu gbe Olorun ga, o wipe Oluwa la oju awon afoju, Oluwa gbe awon ti a te lori ba dide, Oluwa fe awon olododo. Oluwa pa awon alejo mo, o tu awon alaini baba ati opo lara, sugbon ona awon eniyan buburu ni yio daru. (Orin Dafidi 146:8-9)
EKO
Olorun wa dara, oun lo ni ase ti o ga ju ni gbogbo aye. O ni ogbon ati agbara lati se ohun gbogbo, ko si eni ti o ngbaa ni imoran. Ko beere iranlowo enikan ri, nitori oun lo ni gbogbo agbara, o si mo ohun gbogbo. O mo ohun gbogbo, o si lee se ohun gbogbo. Nitori naa, gbogbo eniyan ni lati maa yin in ni gbogbo igba. Je ki alaye okan ke Halleluya.
ADURA
Mo yin o Olorun, nitori iwo ni Oluwa awon Oluwa ati Olorun awon Olorun. Didara re gbooro, ogbon re ko see waadi, Olorun iyanu ni o nigba gbogbo. Iwo ni oko awon opo, aya fun awon alailaya, obi fun awon alailoobi. Ijolotito re lo lati ebute kan de ekeji (Ariwa de Gusu) o gun lati ariwa de gusu, lati ila oorun de iwo oorun. Oluwa mo dupe lowo re fun gbogbo isore re ninu aye mi. E se li ekan si Olorun, mo wipe Amin.
