EMI MIMO; AGBARA FUN ISIN ITEWOGBA
Awon omo Olorun ni lati yerani sise ohun ti Emi pelu iwa ti ara. Sugbon eniyan nipa ti ara ko gba ohun ti Emi Olorun won-on-ni, nitori pe were ni won jasi fun un, oun ko si le mo won, nitori nipa ti Emi ni a fi nwadii won. Sugbon eni ti o wa nipa ti emi nwadii ohun gbogbo, sugbon ko si enikeni tiii wadii re (1 Korinti 2:14-15)
EKO
Emi Mimo ko le joba nibi ti emi ara ba njoba. Ko si le sise bo ti ye larin awon ti Okan won ko ba jinle. Ki Emi Mimo baa le sise re ninu aye wa, a ni lati wa laaye ninu emi, ki a si gba lati sin Olorun bo ti ye. Ni afikun, ko si Kristeni ti o le gbe igbe aye iwa mimo, ki o si je anfani Olorun laisi iranlowo Emi mimo. Nitori naa o se Pataki ki Kristeni lepa Emi Mimo, ki o si maa gbe ni ookan aya won.
ADURA
Olorun se mi ni eni Emi, ki emi ba lee sin O bo ti ye. Jowo parun ninu mi gbogbo ise ara ninu aye mi, ki emi lee maa je awon anfani re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
