ESE
Ese mu ki Olorun ko ehin si oba Saulu ni igba ti o fe iranlowo re ju, Olorun ko lati dahun adura Saulu nigba ogun, o si ko lati fun ni itoni nipa ogun ti nbe. Nitorina Saulu gbojege O wa ona abuja, o si to aboku soro lo sugbon o yori si iparun emi re. Oba Saulu padanu ogun o si ku si ikogun awon ota. Bibeli rohin nipa ojuse oba Saulu ‘Awon Filistini si ko ara won jo, won wa, won si do si Sunemu. Saulu si ko gbogbo Isreali jo, won si tedo si Gilbaa, nigba ti Saulu si ri ogun awon Filistini naa, oun si beru, aya re si wariri gidigidi. Nigba ti Saulu si bere lodo Oluwa, Oluwa ko daa lohun nipa ala, nipa urimu tabi nipa awon Wolii. Saulu si wi fun awon iranse re pe, e ba mi wa obirin kan ti o ni emi abokuusoro, emi o si too lo, emi o si bere lodo re. Awon iranse re si wi fun un pe, woo, obirin kan ni Endori ti o ni emi abokuusoro. Saulu si pa ara re da, o si mu aso miran wo, o si lo awon omokunrin meji si pelu re, won si wa si odo obirin naa ni oru, oun si wipe emi be o fi emi abokuusoro da nnkan fun mi, ki o si mu eni ti emi o daruko re fun o wa oke fun mi.
(Samueli kini 28:4-8) (Samueli kinni 31:1-6)
EKO
Olorun korira ese, o si maa nmu lati gbe igbese ti o le si awon omo re. Nigba ti Olorun nfe ki gbogbo eniyan gboran si oun, ko tun le yipada ki o wa bukun alaigboran omo, eleeda yi o bukun enikeni tabi awon eniyan ti o ba gboran si ofin re, sugbon awon alaigboran ni yi o gba idajo aigboran won. Nitori naa, gbogbo eniyan ni lati beru Olorun, pa ofin re mo, ki a ba le di eni ibukun.
ADURA
Olorun olufe, mase je ki nfi ese mu o binu, kinsi gba idajo re ti o buru pupo. Mase je kinsi ore-ofe re lo sugbon je kin le tele ilana re, ki o ba le dara fun mi nile aye yi. Jowo ran mi lowo lati le ronupiwada ese mi nigbati mo ba rii pe mo se si o ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
