AWON LAALAA RERE RE KO NI LO LAI NI ERE
Bibeli soro nipa awon akinkanju Juu ti won pinnu lati pada wa lati Babiloni wa si ile won ni Israeli, pelu ero lati se atunko tempili Olorun. Awon Juu fi Babiloni sile lati wa se atunko tempili Olorun ni Jerusalem. Won rubo ebo ti o se itewogba si Olorun lehin ti won pari ise won. Bibeli salaye igbiyanju won. Omo awon ti a ko lo, awon ti o ti inu igbekun pada bo, ru ebo sisun si Olorun Israeli, egboro –maalu mejila agbo merindilogorun, odo-aguntan metadinlogorin, ati obuko mejila fun ebo ese; gbogbo eyi je ebo sisun si Oluwa. Won si fi ase Oba fun awon ijoye Oba, ati fun awon bale ni oke odo won si ran awon eniyan naa lowo, ati ile Olorun (Esra 8:35-36).
EKO
Enikeni ti o ba jowo gbogbo aye re fun Olorun, oju koniti labe akoso bo ti wu ki o ri. Won o gba ere fun akitiyan won. Olorun yi o bukun won, nitori ohun ti o nan won. Jehofa yi o san esan fun won. Enikeni ti o ba fi gbogbo okan sin Olorun oju ko ni tii, ogo Olorun yi o maa tan laye won nigba gbogbo. Imole won yi o maa tan titi aye. Nitorina enikeni ti o ba nsise fun Olorun ki o tesiwaju, nitori anfani ti o wa ni ojo ola. Bakannaa enikeni ti ko ba tii maa sise fun Olorun ki o se atunse, ki o baa le gba ibukun lati owo eleda re. Nje o nfi gbogbo ara sise fun Olorun.
ADURA
Olorun olufe igbe aye mi ko ni itunmo bi nko ba fi gbogbo okan sin o. Nitori naa mo pinnu lati sin o ki o baa le gba gbogbo ogo lori aye mi. Jowo fun mi ni okan lati sin o ni otito titi opin aye mi. Ran mi lowo lati sin o pelu irorun, ki ijosin mi si se itewogba ni gbogbo igba. Jowo se mi ni ohun iyin oruko mimo re lati akoko yi ati titi lae. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
