AIGBORAN A MAA JASI IJIYA
Oba Ahabu ni aafin ti o tobi, sugbon o jowu Naboti ti o ni ogba kekere. Oba oloju kokoro yi, gbimo papo pelu iyawo re (Jesebeli)lati pa Naboti. Bibeli salaye isele naa o si se leyin nkan wonyi, Naboti ara Jesreli ni ogba ajara ti o wa ni Jesreeli, ti o sunmo aafin Ahabu Oba Samaria girigiri. Ahabu si ba Naboti so wipe, fun mi ni ogba-ajara re, ki emi ki o fi se ogba-ewebe, nitori ti o sunmo ile mi, emi o si fun o ni ogba ajara ti o sanjuu lo dipo re, bi ko ba si dara ni oju re, emi o fi iye-owo re fun o. Naboti si wi fun Ahabu pe, Oluwa ma je ki emi fi ogun awon baba mi fun o. Ahabu si wa si ile re, pelu okan ti o wuwo, inu re si baje nitori oro ti Naboti awa Jesreeli so fun-un, nitori ti oun ti wipe emi ki o fun o ni ogun awon baba mi, oun si dubule lori akete re, o si yi oju re pada, ko si fe jeun. Bee ni o kowe ni oruko Ahabu, o si fi edidi re dii, o si fi iwe naa sowo sodo awon agbaagba ati awon olola tin be ni ilu re, ti o si nba Naboti gbe. O si ko sinu iwe naa wipe. Ekede aawe, ki e si fi Naboti si ipo ola laarin awon eniyan. Ki e fi eniyan meji, eni buburu, siwaju re lati jeeri paa, wi pe iwo bu Olorun ati Oba, emu un jade, ki e si soo ni okuta, ki o le ku. (1 Awon Oba 21:1 – 4, 8 – 10)'
EKO
Iwa buburu ko dara, Olorun yio si jee niya. Olorun Eledaa yio fiya je eniyan buburu, bi o ti wu ki won ni agbara ati okiki to. Ayafi, ki won ronupiwada, eniyan buburu yio ba ara re ni orun ina apadi, nibi ti idaniloro yio wa titi laelae. Bi o ti je wipe a ko ko oro yi oluse buburu si igboju enikeni, opolopo onise ibi ko mo iru eni ti won je, afi ki won se ayewo ara won finifini. O se Pataki ki olukuluku eniyan ye ara re wo, ki won si se akiyesi ise won. Gbogbo wa nilati ye ara wa wo ninu otito b’oya a ti huwa ibi kan ti a ni lati ronupiwada re. Olorun je Oluferan, o si ndari jinni, yi o dariji, yi o si fun wa ni anfani ni igba keji fun enikeni ti o ba ronupiwada kuro ninu iwa buburu re.
ADURA
Olorun Olufe, jowo dari ji mi gbogbo iwa buburu ti mo ti hu seyin. Mo kaanu fun gbogbo iwa buburu. Mo ronupiwada kuro ninu ise ibi, emi ko ni pada sinu re mo. Mo pinu lati maa se ohun gbogbo bo ti to ati bo ti ye. Emi yi o se idajo ti ko ni ojusaju, emi ko ni re enikeni je fun anfani ara mi. Emi yi o se daradara si awon ti o wa labe idari mi. Emi yi o ni itelorun ninu ohun ini mi, emi ki yi o jowu elomiran. Ranmilowo lati je olotito si o ati si gbogbo eniyan, ki o ba le dara fun mi ni gbogbo ojo aye mi. Ni Oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
