AGBEYEWO ORO OLORUN NIGBA GBOGBO JE OHUN IJA PATAKI FUN ONIGBAGBO
Olorun yan Josua gege bi adari awon omo Israeli, ki o se giri ki o mu aye le. O seleri lati ran lowo lati gba ile ti o seleri fun awon eniyan tire. Olorun so fun Josua ibi gbogbo ti atelese yin ba te, eyin ni mo fi fun gege bi mo ti so fun Mose. Lati aginju ati lebanoni yii, ati titi de odo nla nni, odo eufera, gbogbo ile awon hiti, ati titi de okun nla ni iwo-oorun, eyi ni yoo se opin ile yin. Ki yoo si Okunrin kan ti yoo le duro niwaju re ni ojo aye re gbogbo, gege bi mo ti wa pelu Mose, bee ni emi o si wa pelu re. Emi ki yoo fi o sile beni emi ki yoo ko o (Josua 1:3-5).
Ni afikun, ileri isegun fun Josua, olorun fun ni asiri aseyori; O so fun josua pe yio je alaseyori adari bi o ba le ma se asaro oro re (Bibeli mimo). Olorun wipe saa se giri ki o si mu aya le gidigidi, ki iwo ki o le kiyesi ati se gege bi gbogbo ofin ti Mose iranse mi ti palase fun o, ma se ya kuro ninu re si otun tabi si osi, ki o le dara fun o nibikibi ti iwo ba nlo. Iwe ofin yi ko gbodo kuro ni enu re sugbon iwo o ma se asaro ninu re ni osan ati ni oru, ki iwo ki o le kiyesi ati se gege bi gbogbo eyi ti a ko sinu re, nitori nigba naa ni iwo o se ona re ni rere, nigba naa ni yoo dara fun o. Emi koo ha pase fun o bi? Se giri ki o si mu aya le, ma se beru beeni ni ki aya ki o ma se fo o nitori pe Oluwa olorun re wa pelu re nibikibi ti iwo ba nlo
(Josua 1:7-9).
EKO
Awon omo olorun ni lati ma se asaro lori oro olorun nigbagbogbo ki won ba le di eni ibukun. Oro olorun tii se bibeli fun wa ni imoye ilana ki a si se eyi ti o dara. Nini imo nipa oro olorun, yi o ran Onigbagbo lowo lati le ma se gege bi ilana olorun lati igba ipinlese. Enikeni ti o ba kun fun kikeko oro olorun yi o ri ifami ororo gba lati le ma rin nipa ona ti olorun ni fun igbe aye re. Eyi yio yori si gbigba ibukun olorun. Kikeko oro olorun yi o mu ki Onigbagbo ni agbara lati bori arekereke satani. Enikeni ti o ba nkeko bibeli, yi o ma bori ota, nitori yi o ni imolara arekereke ti satani le ma da, yi o si gbaradi lati ta koo. Ohun kan to tun se Pataki ni pe, nini imo nipa bibeli, yi o nira fun satani lati se idena adura ti a fi ese bibeli ti lehin. Ota a ma subu nigba ti o ba ngbo ti Onigbagbo ba nki adura re lehin pelu ese oro olorun, yi o si fese fee. Niwon igba to je pe opolopo anfani ni o wa ninu kikeko ninu bibeli, Onigbagbo nilati sa ipa ati agbara lati kun fun oro olorun.
ADURA
Olorun olufe se mi ni ojulowo kristeni ti yi o keko oro re lojojumo ki nba le se aseyori. Ran mi lowo lati le ko ati ka oro re nigba gbogbo. Je ki bibeli ko di ore kori ko sun fun mi, ki emi ki o ma sasaro ninu re losan ati loru, ki nba le di eni ibukun ninu aye, ki nsi jogun ijoba re. Je ki oro yin kio mu ki mi maa dan si, ki okan mi ma yo ki nba le saseyori nigbogbo aye mi. Ni oruko Jesu Kristi. Amin.
