ADURA; OPA KRISTENI FUN IYIPADA
Adura a maa yi ohun gbogbo pada, awon omo Olorun ni lati maa gbadura nigba gbogbo. Paulu gbadura fun awon Tesalonika o wipe ki Oluwa si maa mu yin bi sii, ki e si maa po ninu ife si omonikeji yin, ati si gbogbo eniyan, gege bi awa tin se si yin. (1 Tesalonika 3:12)
EKO
Adura je ohun amulo ti o dara lati yanju isoro omo eniyan. Yio so agbara awon ota wa di asan, awon oke ni a o so di petele. Gbogbo Kristeni ni lati ko iha to dara si gbigba adura, niwon bi o ti je ohun elo ti o lagbara lati yanju isoro wa.
ADURA
Olorun Olufe, je ki emi wonu adura ti yio mu ki ohun gbogbo sise si rere fun mi. Mo nlo akoko yi lati beere ki o fun mi ni ifokanbale ni akoko isoro. Je ki emi mu iduro mi sinsin bi Kristeni. Jowo pese fun gbogbo aini mi ni orukoJesu Kristi ni mo beere. Amin.
