ADURA NI OPA KRISTIENI
Dafidi ko lati fi eleran ara se igbekele nigba isoro, o kepe Olorun fun iranlowo O si gba a, nigba isoro Dafidi wipe ‘Saanu fun mi Olorun, saanu fun mi nitori ti okan mi gbeke le o, looto ni ojiji iye apa re ni emi o fi se aabo mi titi wahala wonyii yoo fi re koja. Emi o kigbe pe Olorun Oga-Ogo, si Olorun ti o se ohun gbogbo fun mi, oun o si ranse lati orun wa yoo si gba mi bi eni ti nfe gbe mi mi tile unkegan mi, Olorun yoo ran aanu re ati otito re jade.
(Orin Dafidi 57:1-3)
EKO
Adura je ohun elo ti o se Pataki ti kristieni ni lati lo lojojumo, anilati yin Olorun lakoko adura, a si ni lati so edun okan wa fun un. Ni akoko isoro kii se pe ki a kigbe pe Olorun si irora wa sugbon a ni lati pe Olorun fun ona abayo, adura se Pataki lati pe Olorun si isoro wa, ki o si fun wa ni isegun.
ADURA
Olorun olufe, ko mi bi mo se le gbadura. Je ki unle salaye bi mo se ri ki unsi beere isegun ni gbogbo idojuko mi, si ran igbagbo mi lowo bi mo ba gbadura ki nri idaniloju pe o ti gbo adura mi. jowo fun mi ni ore-ofe awon anfani ti unbe ninu adura, ki o si dara fun mi ni gbogbo igbesi aye mi. ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
