PATAKI WIWASU IHINRERE
Jesu Kristi fi ounje sile ki o ba le waasu ihinrere. O ka iru ayekaye ti o ba ri lati wasu ihinrere si bi isura, o si nloo lati mu ki ijoba Olorun maa po sii. Nigbati awon omo ehin re ro o ki o jeun, Jesu wipe emi ni ounje lati je, ti eyin ko mo, nitori naa ni awon omo ehin re nbi ara leere wipe, enikan mu ounje fun un wa lati je bi? Jesu wi fun won pe, ounje ni mi lati se ife eni ti o ran mi, ati lati pari ise re. (Johanu 4:32-34).
EKO
Awon omo olorun ni lati ni lokan ni gbogbo igba , bi won se le te olorun lorun, ohun yio wu ti yio na won. A ni lati keko lara Jesu Kristi ti ko ta ise iranse re pelu ohunkohun. O ko lati jeun, ki o ba le ri aye fun wiwaasu ihinrere (Johanu 4:32-34). O si ko isinmi rampe sile.
Akoko ko duro de enikan, gbogbo omo olorun ni lati lo gbogbo akoko ti a ni lati waasu ihinrere. O le ma si akoko itelorun, nitorina, e je ki a lo ayekaye lati kede ihinrere. Gbogbo kristeni lo ye ki a waasu ihinrere Jesu kristi fun gbogbo eniyan. Boya akoko wo tabi ko wo fun wa. Bibeli salaye pataki ninu wiwaasu ihinrere (2Timotiu 4:1-5). Olorun seto ekunrere ibukun re fu enikeni ti o ba nwaasu Kristi fun awon elomiran.
ADURA
Olorun olufe, jowo fun mi ni agbara lati maa waasu ihinrere ni gbogbo akoko, boya o rorun tabi ko rorun. Ranmilowo lati mo pataki wiwaasu, si ranmilowo lati waasu ihinrere fun itelorun re. Fun mi ni ifami ororo yan ore ofe lati salaye ihinrere ni ona ti yi o so eso rere sinu ijoba re. Bi mo se nwaasu, je ki awon alaigbagbo yonda igbagbo won fun Jesu Kristi ki won si di eni igbala.
Ni afikun, jowo bukun mi, ki emi si ri ere gbigboran si ase re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
