OPIN KONI PE DE
Bibeli gba Kristeni ni imoran lati fokan si ayo ayeraye ti o nduro de wa ni orun. A ni lati koju si Jesu Kristi, ki ohun mere mere aye ti yio wa fun igba die ma ba gba wa lo. Bi a ti koo wipe, nje bi a ba ti ji yin dide pelu Kristi, e maa saferi awon nnkan tin be loke, nibi ti Kristi gbe wa ti o jokoo ni owo otun Olorun. E maa ronu awon nnkan tin be loke kii se awon nnkan tin be ni aye. Nitori eyin ti ku, a si fi iye yin pamo pelu Kristi ninu Olorun. (Kolese 3:1-3)
EKO
Ile aye ti a wa yi ko jamo nkankan, bikose oja ti o kun fun orisirisi ohun ti won npe akiyesi wa, Kristeni ni lati sora, ki a mase ko si pampe won. Awa Kristeni ko gbodo so ogbon ti Emi sonu, ninu sise wa ninu aye. A ni lati wa ninu Emi ki a ko Satani ati idanwo re sile. Bakanaa a gbodo para run, ki a baa le sa fun ese. Bibeli rowa ki a gba igbe aye iwa mimo laaye bi a ti koo ninu Kolose 3:5. Nitori naa, e maa pa eya-ara yin tin be ni aye run, agbere iwa-eeri, ifekufe buburu, ati ojukokoro, tii se iborisa. Ni afikun, Bibeli salaye nipa ojuse ara ati Pataki amuye fun orun ninu Kolose 3:12-14 ‘Nitori naa, bi ayanfe Olorun, eni mimo ati Olufe, e gbe okan iyonu wo, iseun, irele, inu tutu, ipamora. E maa fara da a fun ara yin, e se maa dariji ara yin bi enikeni ba ni esun si enikan, bi Kristi ti dariji yin, gege bee ni ki eyin ki o maa se pelu. Ati bori ohun gbogbo nnkan wonyi, e gbe ife wo, tii se amure iwa pipe. (Kolose 3:12-14)
ADURA
Olorun Olufe, mo loye pe Kristeni ti je sise ise, ju pe ki a je afidi gbon ijoko lo. O fe irubo ju isin ete lo. A ko ni se odiwon igbagbo mi pelu iye Bibeli mimo ti mo ni, tabi iye ise esin ti mo nse. Iwo nfe okan ti o fara ji pelu okan ikaanu. Emi yio tele Bibeli, ma si maa rin ninu iwa-mimo. Jowo ro mi ni abgara Emi-Mimo, ki emi le kunju ireti re lodo mi, ki emi le ye fun ijoba re. Ni oruko Jesu Krist ni mo beere. Amin.
